Aṣikiri mẹdogun ku lehin ijamba ọkọ oju-omi ni eti okun Libya
Bii awọn aṣikiri mẹdogun ti n gbiyanju lati de Yuroopu ti rì sinu Okun Mẹditarenia ni etikun Libya, ajọ International Organization for Migration (IOM) lo sọ bẹ.
Ọkọ oju-omi aṣikiri na ti o kuro ni iwọ-oorun ilu ti Zawya ni Ilu Libya ni ọjọ kejidilogun oṣu kẹwa daanu ni etikun. Bii marun ninu awọn aṣikiri naa ni awọn apeja gbala ti wọn si mu pada si ilu Sabratha ni ogun ọjọ oṣu kẹwa, Safa Msehli, agbẹnusọ fun IOM sọ.
O ju aadọrin awọn aṣikiri ni awọn ẹṣọ eti okun mu ti wọn si da pada si Libya, ni ibamu si Federico Soda, olori iṣẹ IOM ni Libya.
Laarin Oṣu kini ati Oṣu kẹwa ọdun 2020, o ju awọn aṣikiri igba ti o ti rì beeni awọn bi igba o le ọgọrin miiran ti sọnu nigba ti wọn n gbiyanju lati sọda Mẹditarenia si Yuroopu, IOM lo sọ bẹ. O ju 9,800 awọn aṣikiri lọ ti o ti pada si Libya.
TMP_23/10/2020
Image Credit: Shutterstock/Riccardo Nastasi
Image Caption: Abandoned migrant boat
Pin akole yii