Didekun awọn iró lori Coronavirus

Ọpọlọpọ iró, ọrọ agbọ sọ ati alaye ti ko n ṣe ododo ni n kaakiri laarin awọn aṣikiri nipa COVID-19. Fun iranlọwọ lati le jẹ ki o gbe igbesẹ  ti o tona, a ti ṣe akojọpọ awọn iró ti o wọpọ julọ ki o ba le ni imọ lati daabobo ararẹ lakoko ajakaye-arun COVID-19. Fun alaye diẹ sii ati awọn alaye lori awọn iró ti o wọpọ kaakiri nipa COVID-19, ṣabẹwo si oju ewe World Health Organization ti n dojukọ awọn iró naa.

Iró: Ajakaye-arun COVID-19 ki n ṣe ooto

Awọn ọrọ agbọsọ n tan kaakiri lori social media pe iró ni arun COVID-19. Laarin idi ti awọn eniyan sẹ n sọ bẹ ni wi pe won gbagbọ pe China tabi Russia ni o ṣẹda ajakaye-arun naa lati ni agbara ati ọrọ aye sii.  Eyii jẹ iró – COVID-19 wa ni tooto. Ẹri lati ọdọ awọn onimo ijinle sayensi fihan pe awọn eniyan ko arun na lati ara ẹranko. Awọn statistiki ti osise lati ajọ World Health Organization fihan pe arun naa ti mu miliọnu  awọn eniyan ni agbaye.

Iró: Arun naa ko le yè ni ayika to ba gbona

Ọrọ agbọsọ miiran ni pe COVID-19 ko le yè ni ilu to ba gbona bi Afirika. Ajọ World Health Organization sọ pe arun naa le tan ni ibikibi, yaala orilẹ-ede ti o ni oju ojo gbigbona tabi tutu. Ọpọlọpọ eniyan ni o ti ni arun coronavirus ni awọn orilẹ-ede gbigbona bi Saudi Arabia ati pupọ julọ ti Guusu ila oorun Asia. Ko si ẹri kankan wipe arun naa yi o ku ti o ba sa ararẹ si inu oorun fun akoko pipẹ. Awọn amoye sọ pe oju ọjọ gbọdọ gbona ju iwọn 140 Fahrenheit lọ lati pa arun yii.

Iró: Ijọba o sọ ootọ nipa nọmba awọn ti o ni arun COVID-19

Iroyin sọ pe oṣeeṣe ki awọn orilẹ-ede kan n ṣe idinku iye awọn ti o ni arun COVID-19 ati awọn ti o ti ku nipase arun naa. Ni awọn orilẹ-ede ti ko ni awọn eto to peye tabi agbara lati ṣe idanwo daradara, o le nira lati mọ daju iye awon ti COVID-19 ti pa. Fun imọran to peye lori ipo agbaye, Ajọ World Health Organization ati The European Centre for Disease Control and Prevention (ECDC) n ṣe atẹjade awọn iṣiro lojojumọ lori ajakaye-arun COVID-19.

Iró: Awọn ijọba oni’baje n lo arun COVID-19 lati ko owo je ati lati gbẹsẹ le ẹtọ awon omo ilu

Awọn eniyan kan sọ pe ajakaye-arun COVID-19 jẹ ete ijọba lati ma fẹ san owo osu awọn oṣiṣẹ ijọba ati mase se le nawo sinu idoko-owo. Ni otitọ, COVID-19 je iṣoro ti o mu awọn ijọba ni agbaye lati nawo gan ti wọn si di onigbese lati le ṣetọju sisan owo awọn oṣiṣẹ, awọn iṣẹ ipilẹ ati ilera-aabo. COVID-19 duro fun irokeke awuye si ilera gbogbo eniyan ni agbaye.

Iró: Awọn ọmọ Nigeria kan gbagbọ pe COVID-19 jẹ idajọ lati ọdọ Ọlọhun si awọn adari ilu ati awọn oloselu.

Ni Naijiria, ọrọ agbasọ n tan kaakiri pe COVID-19 jẹ ajakalẹ arun fun awọn adari ilu ati pe ọna Ọlọrun ni lati mu ayipada wa si ijọba. Eyi ko ṣeeṣe notori wipe COVID-19 n mu enikeni laisi lai ya enikeni sile. O jẹ eewu fun awọn ọlọrọ ati talaka, ati awọn ti o wa lati awọn agbegbe ti ko ni nkankan – nibi ti iyara eni sọtọ ni awujọ ko ṣeeṣe – wa ninu eewu pelu. Ipo ni awujọ ko ni ipa lori ẹniti o ni arun yii bi o tilẹ jẹ pe ẹri diẹ wa pe ipo ni awujọ ati ipo ọrọ yoo ni ipa boya o le yè laaye tabi rara.

Iró: Awọn ara Africa ko le ni arun naa

Ni awọn orilẹ-ede kan, bi Nigeria, awọn ọrọ agbasọ n tan kaakiri pe awọn eniyan ko le ni arun naa. Eyi kii ṣe otitọ. Iwadi lati ọdọ World Health Organization fihan pe o fẹrẹ to 200,000 eniyan ni Africa ni o wa ninu ewu lati ku nipase COVID-19 ti ko ba ṣakoso. Ni iwoye, dabi pe COVID-19 n tan diẹ diẹ kaakiri ni Afirika ni afiwe si awọn orilẹ-ede miiran nitori ọpọlọpọ awọn ọdọ ti o wa ni Africa ati wipe ko si ọpọlọpọ awon eniyan sisanra ju ni Africa, ni ibamu si iwadii lati ọdọ WHO.

Iró: Awọn ọlọrọ ni iwosan fun COVID-19.

Lọwọlọwọ, ko si iwosan fun COVID-19. Awọn onimo ijinlẹ sayensi kakiri agbaye n ṣiṣẹ lọwọlọwọ lori oriṣiriṣi ajesara ati itọju fun arun COVID-19. Ọna kan ṣoṣo lati dekun itankale arun naa ni lati tẹle imoran ti ajo World Health Organization bi fifọ ọwọ rẹ nigbagbogbo ati yiya ara ẹni sọtọ ni awujọ.

Iró: Egboigi le wo COVID-19 san

Ko si ẹri pe awọn apejọ egboigi, bi ata ilẹ tabi mimu omi iyọ, yoo ṣe iwosan COVID-19. Bi o tile je pe diẹ ninu awọn egboigi le ni awọn anfani ilera miiran, lọwọlọwọ ko si iwosan fun COVID-19. Ọna kan ṣoṣo lati dekun itankale arun naa ni lati tẹle imoran ti ajo World Health Organization bi fifọ ọwọ rẹ nigbagbogbo ati yiya ara ẹni sọtọ ni awujọ.

Iró: Mimu oriṣiriṣi kẹmika le pa arun naa.

Mimu awọn nkan ipalara bi Bilisi tabi kẹmika abi mimu ọti pupọ ko le pa arun naa o si le ni awọn abajade to buru gan ati paapaa ja si iku. Fun apẹẹrẹ, ni Iran o fẹrẹ to awọn eniyan 300 ni o ku leyin aisan lati mimu methanol nitori ọrọ agbasọ  eke wipe o le ṣe iwosan fun arun naa. Awọn idanwo oogun pupọ n lo lowo lati wa iwosan fun COVID-19. Ọna kan ṣoṣo lati dekun itankale arun naa ni lati tẹle imoran ti ajo World Health Organization bi fifọ ọwọ rẹ nigbagbogbo ati yiya ara ẹni sọtọ ni awujọ.

Iró: Wiwọ aṣọ iboju ko ni je ki o ni COVID-19

Awọn aṣọ iboju ko tunmọ si wipe o ko le ko arun naa ṣugbọn oun ṣe idiwọ fun arun naa lati tan kaakiri nipa didena awọn isọ si awọn ikọ ati imu. Ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede ti ṣo wiwọ aṣọ-iboju di dandan lati le ṣe idiwọ fun itankale arun naa. Awọn iboju ni ipa pataki ninu idilọwọ itankale arun naa pẹlu fifọ ọwọ loorekoore ati ṣiṣe adaṣe awujọ

Iró: Nini COVID-19 ko buru ju nini otutu lọ

COVID-19 je arun ti o le gan nitori o ni oṣuwọn pipa eniyan ju aisan otutu lọ. Milionu eniyan ni agbaye ti ku nipase COVID-19. Diẹ ninu awọn eniyan ti o ni arun na le ni ami kekere tabi iwọntunwọnsi, awọn miiran ni iriri awọn aami aiṣan pẹlu awọn iṣoro mimi ati pe o nilo lati wa ni ile-iwosan. Awọn agbalagba ati awọn ti o ni aiṣoro mimi wa ni ewu ti o pọ diẹ sii ṣugbọn COVID-19 tun le mu awọn ọdọ.