Ti o ba jẹ aṣikiri tabi eniyan ti n wa aabo ni orilede omiran nigba ajakaye-arun COVID-19, oju-iwe yii ṣalaye bi o ṣe le wa alaye diẹ sii lori bi o ṣe le daabobo ararẹ ki o si wa l’alafia.
Itaniji lori ilera ti World Health Organisation lori WhatsApp
n pese alaye pataki lori COVID-19 lati ṣe iranlọwọ lati jẹ ki awọn eniyan ni aabo lakoko ibesile aisan agbaye yii. Eto naa ri si alaye lori awọn aami aisan ti COVID-19 bakanna bi awọn eniyan ṣe le daabobo ara wọn ati awọn to wan wa ni ayika wọn.
Eto naa jẹ ọfẹ o si le loo nipasẹ titẹle awọn igbesẹ kekere wọnyi:
Nitori ajakaye-arun COVID-19, ọpọlọpọ orilẹ-ede ti di awọn aala iwọle ati ijade wọn ni igbiyanju lati dekun iṣọrọ naa.
Eyi ni ipa gidi lori awọn aṣikiri ti o rinrin-ajo tabi ti wọn gbe laarin awọn ilu naa.
Abajade eyii ni wipe, ọpọlọpọ awọn arinrin-ajo ni idiwọ lati kuro ni awọn ibudo ati agọ gbigba nitori awọn idiwọ titiipa ati ijoko sile. Ajakaye-arun naa tun nfa igara lori awọn ijọba ati awọn ẹgbẹ ti ko nse ti ijọba sugbon ti o ṣe iranlọwọ fun awọn ti o wa aabo ni orilede miran. Lapapọ, awọn ti o wa aabo ni orilede miran yẹ ki o reti awọn idaduro ati awọn igbese afikun ti o le ṣe idiwọ sisẹ awọn ibeere wọn ni akoko yii.