Germany n gbero lati da egberun lona ogbon omo Nigeria arinrinajo laibofinmu pada sile
Ijoba ile Germany n gbero lakotun lati fi ogbon egberun awon omo orile ede Nigeria awolu laibofinmu sowo pada sile.
Igbese naa loje okan ninu igbese lati satunse si eto tonlo lowo eyi ti ile Germany lero wipe o n wole pupoju.
Minisita to n risi oro ile okeere nile Nigeria, Geoffrey Onyeama, eni ti o se ipade pelu oga oludamoran to n risi eto aabo fun aare ile Germany, Dr. Jan Hecker ni olu ilu Nigeria lati fenu oro jona lori igbese na.
Onyeama so wipe ile Germany koro oju pelu iye onka awon aririnajo lona aito ati awon ton Fe lati farasin silu naa lati ile Nigeria atipe won ti so ireti nu ninu eto dida pada awon arinrinajo naa.
Lowolowo bayi, awon omo orile ede Nigeria ti won n fe lati farasiń si orile ede Germany ni lati se bee nipase ile ejo, won yo yewon wo daradara sugbon ti wo ba gbawon wole won le pe fun atunyewo idirebe won.
Nigbati gbogbo anfani ati akitiyan won ba ja si pabo, ijoba ile Germany yo kan si ijoba orile ede Nigeria lati se agbedide iwe eri arinrinajo pajawiri kiakia lojuna ati da awon arinrinajo na pada sile, idi ni pe lopolopo igba won kii ni iwe irinajo lowo.
“Awon ara Germany n so di mimo wipe asiko ti ile ise arinrinajo Nigeria ati alase re nlo lati se eto yi ti npe ju botiye lo atipe opolopo ise ti awon alaàto na n se ni o je atunse lasan si ohun ti ile Germany ti se seyin “Onyeama so eyi fun iwe iroyin Deutsche Welle.
Gege bi Onyeama se so, eto tuntun na yo f’opinsi idaduro towa laarin boya arinrinajo to si fifisowo pada sile leyin ti o ti padanu gbogbo anfaani toni labe ofin eyi ti yoo fi aye gba ijoba ile Germany lati da aririnajo naa pada sile lai nilo ifiwosi ijoba ile Nigeria.
Onyeama tun so siwaju pe aato titun na je okan gbogi ti yo mun iyato ba aato to wa nile tele. O so wipe ile Germany yo ma fun awon aririnajo ti won fi sowo pada sile na ni awon iwe irinajo atipe yo ma risi inawo won bakanna.
“Ohun ti mo fe lati fi rinle nipe aato na yoo nilo lati se ayipada si awon ofin iwe irinna wa fun awon omo orile ede Nigeria leyi ti yo si se afojufo awon ojuse kan fun ajo irinna wa ati adari re ninu fifisowo pada sile awon omo Nigeria. Lowolowo bayi, awon ajo irinna ati ile ise wa farajin si atunse yii. “won yoo ma fun won ni iwe arinrinajo nigbati ipinnu ba ti je sise lati fi arinrinajo sowo pada sile ” o fi rinle be.
Bakanna ni Onyeama so wipe ni bi odun meji to koja seyin, igba arinrin ajo pere loti pada si ile ninu omilengbe egberun lona ogbon omo orile ede Nigeria ti ijoba orile ede Germany ti dajuso fun fifi sowo pada sile.
Orisun Aworan: NaijaGists.com. Awon omo arinrinajo omo Nigeria ton wa idabobo ni ilu Germany
TMP – 28/05/2018
Pin akole yii