Eto asiri yi nse afihan bi The Migrant Project ń śe amulo ati idaábobo eyikeyi ifitonileti ti o ba fun The Migrant Project nigbakugba t’oba lo itakun agbaye yi.

The Migrant Project mu ni dandan lati ri daju pe awon ohun asiri yin je didaabobo. Nigbakiìgba ti a ba beere fun eyikeyi ifitonileti fun idanimo nigbati o ba n samulo itakun agbaye yii, nigba na anfi da yin loju wipe awon ifitonileti naa yoo di lilo ni amuye pelu ero eto asiri yi.

The Migrant Project le s’ayipada eto asiri yì nigba kiigba nipase sise atunto si oju ewe yi. Maa sabewo si oju ewe yii lati rii pe inu re dun si awon atunto wa loore koore.

Awon ohun ti angba sile

A le gba awon ifitonileti wonyi sile:

 • Apejuwe ti a le fi kan si e, lapere, adiresi ero itakun agbaye re (email), ti o ba fi ibeere sowo siwa
 • adiresi ifinihan lori itakun agabaye (IP) re
 • ifitonileti lori bi o sé ń samulo itakun agbaye wa

Ohun ti anfi awon ifitonileti ti a n gba se

A n fi awon ifitonileti wonyi se mimo awon ohun ti o fe ati lati mu idagbasoke ba itakun agbaye yi. A ko lee se idanimon enikeni pelu ifitonileti ti o ni lodo wa.

Oro nipa Aabò

An fi rinle wipe a mu eto aabo ifitonileti yin lokunkundun. Lati le didaabo bo awon ifitonileti re kuru lowo awon alasilo, a ti se eto idaabobo to lowura lati pinwon lowo iru igbese bee atipe, won kole ni anfani lati ribi towobo awon ifitonileti ti angba lori Itakun agbaye wa.

Bi a se nlo cookies

Cookie ni ètò pelebe kan ti n se’beere lati wa lori ero ayara bi asa re. Nigbati o ba fun un lase lati se bee, ètò naa yoo duro sori ero ayara bi asa re atipe cookie yio ma safihan lilo-bibo lori ero yin ati awon itakun agbaye ti o ba sabewo si. Bakanna, cookie yio mu rorun fun edfro itakun agbaye lati ba e soro lona ti e nife si julo nipase sise afipamo awon ohun ti o fe ati eyi ti o ko fee.

An se amulo lilo-bibo ti aba gba lati odo cookie lati se idamon oju ewe wo ni pato ni o nlo ju. Eyi ni yoo ranwa lowo lati mo ohun ti a lese ti a o file te o lorun siwaju sií nigba ti o ba n samulo itakun agbaye wa. A nlo awon ifitonileti wonyi lati se igbelewon lason ni, ti aba ti pari igbelewon wa a ki yoo fi ifitonileti cookie na pamon rara o.

Lakotan, étó cookies n ran wa lowo lati te o lorun pelu itakun agbaye wa nipase sise afihan ni pato, eyikeyi oju ewe ti o wulo fun e ati eyi ti ko wulo. Cookie ko fun wa ni anfaani eyikeyi lati tojubo ero ayara bi asa re tabi eyikeyi ninu ifitonileti e, yato si eyi ti o ba finnu findo lati fi to wa leti.

O le finnu findo lati gba cookie wole tabi ki o ko jale. Pupo ninu awon irinse aamulo wo itakun agbaye lo ma n sadede gba cookie wole, sugbon o le ko jale lati gbaa wole nipase sise atunse si awon irinse aalo re. Ranti pe eyi le se idiwo ranpe fun lilo itakun agbaye re.

Itakun si awon itakun agbaye miran

Itakun agbaye wa le ni awon itọkasi ti yoo gbe e lo si awon itakun agbaye miran to o le nife si. Sugbon, nigbati o ba lo awon itọkasi yi ti o si fi ori itakun wa sile, a ko ni ipa kankan lori itakun tuntun ti o ba jasi o. Nitorina, a ko le dahun fun eyikeyi asemase to ba waye nipase awon ifitonileti ti o ba fi sile ni awon itakun agbaye na nitoripe itakun agbaye naa kosi labe ofin tiwa yii. A n ro o ki o f’arabale lati wo eto asiri itakun agbaye naa.

Sise amulo ifitonileti re

A ko ni fi ifitonileti e sowo si enikeni ayafi ti ofin ba beere lati se bee. A ko ni salabapin awon ifitonileti yin pelu ajo eyikeyi fun itaja, isewadi tabi oro ajè atipe a ko ni fi sowo si awon itakun agbaye miran.

O le beere fun awon ifitonileti ti o fi sile pelu wa nipa e nibamu si ofin ton daabo bo igbasile ti odun 1998. Owo tasere ni o san. Ti o ba fe gba ilewo awon ifitonileti re to wa pelu wa jowo ko iwe sowo siwa ni admin@themigrantproject.org. Bakanna, o le paa lase funwa lati mase lo eyikeyi ifitonileti ti a ba gba nipa re.

Cookie ati bi o se le j’anfaani re

Itakun agbaye wa n samulo cookie gegebi opolopo itakun agbaye se n loo bakanna, lati ran wa lowo fun itelorun re. Cookie je étó kan ti yoo duro s’ori ero ayara bi asa tabi ero ibani soro re nigba ti o ba sabewo si itakun agbaye.

Cookie wa n ranwa lowo :

 • Lati jeki itakun agbaye wa sise bi o se fe
 • Ranti aayo re nigba ti o ba s’abewo tabi o ba nlo itakun wa
 • Sise alekun yiyara ati didaabo boo itakun agbaye wa
 • Ran o lowo lati se alabapin awon oju ewe wa pelu ore re lori ero ibanid’ore bii fesibuuku (Facebook)
 • Mimu itakun wa dara nigba gbogbo
 • Ran wa lowo lori ipolowo wa ( nipase fifi idiyele wa rinle bi a se fe)

A ko lo cookie lati:

 • Gba idakonko ifitonileti (lai funwa lase lati se bee)
 • Gba ifitonileti to lewu (lai funwa lase sisebe)
 • Fi igbasile na sowo si awon olu polowo oja
 • Fifi ifitonileti to fojuhan ranse si alagata
 • San owo oya lori oja tita

O le mo siwajusi lori iru cookies ti anlo nisaleyi

Fifi aaye gbawa lati lo cookies

Ti eto lori aalo ti efi n sabewo si itakun agbaye bawa ni pipa lase lati gba Cookie laaye a o gbaa, atipe o ni anfani lati lo itakun wa siwaju sii, itumon eyi ni pe, e nife si ohun ti o ri lori itakun wa. Ti o ko ba nifesi lati lo cookie lori itakun wa o le ko bi o se le dekun re nisale yi, sugbon o ni lati mon wipe itakun wa ko ni sise bi o se fe ti o ba dekun cookie o.

Cookies wa:

A se amulo cookie lati jeki itakun agbaye we sise nipase:

 • Riranti ohun ti o ti wa seyin

Kosi bi o se le ko cookie yi sile ti o ba samulo itakun agbaye wa.

Cookie ti o le lo lati kan si ara ati ore

Eleyi lo mu rorun fun e lati fi awon oju-ewe wa sowo si ore re lori awon ero ibanid’ore bii fesibūku (Facebook) ati Tuwita(Twitter) pelu tite botini ti a ti pese sile fun e.

Awon alakoso cooki:

Fikun – Eto asiri funwa ni anfaani lati s’alabapin nipase awon botini sinu akojopo kan pere.

Ewu to ro mo idakonko kookan yato nibamu si ero ibanid’ore kookan ati eto ti e ba yan lori won.

Cookie ton risi akasile olusabewo ti a ko mon

A nlo cookies lati se akasile awon olusabewo lapere, eeyan Melo lo sabewo si itakun agbaye wa, iru ero wo si ni wonlo ju (eyi n ran wa lowo lati so ni pato boya itakun agbaye wa n se daada pelu gbogbo ero), bawo ni won se pe to, oju ewe wo ni won n wo ju ati bee bee lo. Eleyi yoo ranwa lowo pupo lati jeki itakun agbaje wa dara si. Eto isagbeyewo yi yo tun fihan wa bi awon olusabewo ti a ko mo se n wa si ori Itakun agbaye wa (lapere, se ero ton sawari nkan ni won lo tabi ohun ko) atipe se won ti sabewo ri. Awon agbasile yi yoo funwa ni anfaani to po lati na owo sibi toye.

Pipa étó cookie

Nigbakuugba to ba wu e, o le pa cookie nipase sise asayan nibi aalo e lati ma fi aaye gba cookie (Ni imo si). Sisebee le di jijafara ati jijafafa awon itakun agbaye lori ero ayarabiasa ku jojo nitoripe cookie je okan gbogi ti o n mu awon itakun agbaye dara ni aye oni.

Otile le jepe iyonu ti en ni lori cookie ni o nii se pelu ohun ti a n pe ni “spyware” (alatojubo lori ero ayara bi asa re). Toba jebe, o lee se awari alo kan to le se alatako fun cookie lori awon igbese re kan nipase pipare ni kiakia leyin ti o ba ti sabewo si awon itakun agbaye ti o bafe. Ni imo si lori bi ati seto cookies pelu eto ton gbogun ti alatojubo.