Eto imulo ajo isokan ile alawofunfun EU: Iha wo lo ko si ile Afirika
Ajo ile alawofunfun EU ti n se akitiyan olokan o jokan lati wa ojutu kan gbogi si isoro ominlengbe awon arinrinajo ti ko b’ofinmu ti won n wo ile na. A tile le jeri si eleyi nipase awon ofin orile ede tuntun ti won ti n gbe jade bakanna bi o se jepe awon egbe oselu ti won se ipinnu lati gbogun ti iwolu lona aito ni won bori ninu awon eto idibo. Aridaju wa pe ile Afirika je okan pataki ninu awon ti aje iwa na simonlori.
Lati bi odun meta seyin, oro wiwo ilu lona aito ni o je ohun ti won n kominu pelu ni ile alawofunfun, awon oluwo lati ile Afirika, ati awon ogunlende lati orile ede Syria. Ni odun 2015 ti iwa na gogo julo, o le ni milionu kan awon arinrinajo lona aito ti won wo ile alawofunfun nipase oju omi nibiti ati ri awon arinrinajo ti won to egberun merin ti won teri sinu omi. Ni odun 2016 nikan, o le ni otaleloodunrun egberun awon arinrinajo ti won forilaku wo ile na gegebi awon emi kan se sofo danu. Ni odun 2017, idaji awon eniyan ti won rapala wole ni odun to koja ni akosile tun fi han pe won wo ile alawofunfun na.
Afirika ni o ni awon arinrinajo ti po julo, nibiti ati ri egbeegberun awon arinrinajo, papajulo lati orile ede Nigeria, Libya, Niger, Tunisia, ati Gambia ti won n wa ibi ti oroaje ti ro somun ni ile alawofunfun, bakanna ni a tun ri awon omo orile ede Burundi, Eritrea ati Sudan ti awon na n fe lati se atipo ni ile alawofunfun nitori ai jagaara eto oselu tabi wahala ogun ti o n sele ni orile ede won. Eyiowuawi, awon isi arinrinajo meji ti a wi yi n se nkan meji papo – won f’ojusun ile alawofunfun lati tedo si nipase gbigba ona ti o lewu ninu.
Bi aba ni ki a daa laba, bi ogooro awon arinrinajo lona aito se n wo ile alawofunfun ni o ti di koko oro ninu oselu, mini isoju selu, ninu awujo ati oroaje fun awon ijoba, awon omo orile ede ile alawofunfun koda, awon orile ede ile Afirika ko gbeyin. Eyi lo mu ki ipago alojo meji laarin awon adari ile alawofunfun mejilelogbon kan way ninu osu kefa odun yi.
Ninu ipago na, awon adari ile alawofunfun na menuba okanojokan ona ti won yo lo lati gbogun ti iwolu laibofinmu ninu eyi ti o seese ki won se agbedide “awon gegele oludanipada” si awon orile ede aresepa lojuna ati ma se iyato laarin awon ogunlende ti won nilo eto aabo ati awon arinrinajo gbefe, ti won ni lati ma dapada si orile ede koowa won ki won to de ile alawofunfun.
Fun ile Afrika, eyi tumon si pe ile alawofunfun n gbero lati gbe awon ibudo ayewo kale ni awon orile ede ariwa ile afrika ti won je ibi ategun tabi oju ona fun awon arinrinajo ti won fe wo ile alawofunfun nipase okun Mediterranean.
Ti erongba na ba jo, eyi yo mu ki awon ti n jalaisi Lori okun Mediterranean dinku jojo, bakanna ni yio tun bu omitutu si okan awon afinisowo, awon agboogun oloro ati awon ti won ban gbero lati gun le irinajo na.
Sibesibe, ile ise iroyin Euractiv fi lede pe opolopo awon olori orile ede to wa ni gusu ile Afrika ni won ko erongba ile alawofunfun na lati se agbende awon ibudo ayewo ni ile Afirika. Koda ajo isokan ile Africa (AU) se be bakanna. Sugbon, ajo AU gbe erongba kan jade lati da ajo ti yo ma risi ayewo fun awon arinrinajo onidagbasoke (OAMD), eyi ni yo je irinse tuntun lati se amojuto ati afiyesi igbokegbodo irinajo sise ni ile Afirika.
Awon ohun miran ti won fi enu ko si ninu ipago ile alawofunfun na ni bi won se fe ki gbogbo awon orile ede ti o ba je arawon da “ibudo ikojanu ” sile kaakiri ile alawofunfun lati ri daju pe “won n se aato ati aabo” to ye lori awon asatipo ati awon oluwo.
Awuyewuye nipa bi won yo se f’opinsi yiyawole awon arinrinajo lati ile Afirika nipase okun Mediterranean wo ile alawofunfun ni o ti fa iyapa laarin awon orile ede ile na atipe, ipago to waye ninu osu kefa tile le ma to lati fenuko si ipinnu kan soso lori oro na. Botilewu kori lojo iwaju, o daju gbangba pe ajo ile alawofunfun ti setan lati se ohun kan gbogi lati pin ogooro awon arinrinajo lona aito lowo ninu erongba won lati wo ile naa.
TMP – 02/08/2018
Photo Credit: www.thesun.co.uk. Oludari Alakoso Germany Germany Angela Merkel ati Aare Faranse Emmanuel Macron lẹhin ti EU gba adehun kan lati mu irora iṣan ni June
Pin akole yii