Awọn aṣikiri Africa ti o ni idaamu ni Libya gba iranlowo lati awọn ajo agbaye

Tobajepe iroyin ti awon to daride lati ilu Libya fi n towa leti ri bee, egbeegberun awon arinrinajo lo si n dojuko ewu nla n’ilu naa lowolowo.

Omo odun meedogbon ni Deola osi je omo bibi ipinle ogun to daride lati ilu Libya ni ojoketadinlogbon osu kejila sowipe won tile fi da ohun loju pe ile amerika ni ohun n lo sugbon oro ko ri bee mo nitoripe ohun di tita si oko eru alasewo ni gere tï ohun wo ilu Libya.

“Iriri mi ninu ageju je ohun to buru jae debi pe nko fe ranti re mo rara. Koda nko mo ibi ti nko ba ti bere tabi danuduro nitoripe b’omode ba debi eru, o di dandan keru o baa”.

Gere ti a wo ilu Libya, won so funmi wipe moni Lati san egbeta owo dinaaru lati le san owo ti won fi gbemi wo ilu Libya lati Nigeria pada. Ni ojo keji, mobere ise asewo botilejepe nko nife si rara. Mo fojukan opolopo nkan ti nko lee fenuso, koda, bi eru ni won se muwa, bi a ba ri enikan ninu wa ti ara re ko baya won ko ni toju re rara nitoripe opolopo awon miran loti la iru idojuko naa koja. ” o so eyi fun okan ninu awon osise to n risi irin ajo.

Eyi ati awon idi miran ni ajo isokan ile afirika AU, ajo isokan ile yuroopu EU ati ajo isokan awon orile ede ri ti won fi gbe igbimon kan kale lati maa gbogunti ati daabo bo igboke-gbodo awon omo afirika ti won lee maa jiya ni ilu Libya.

Leyin ipade awon igbimon naa l’osu to koja ni addisi Ababa, eyi to je olu ilu Ethiopia, eni to je alamojuto eto afe ninu ajo isokan ile Afirika AU to tun je alamojuto pataki kan s’ilu Libya, Amira Elfadil, so fun awon oniroyin wipe awon arinrinajo to boha silu Libya si nilo amojuto gidigidi. Paapajulo, awon arinrinajo ti won WA ni ahamo aladani kaakiri tabi ti won wa lowo awon ajijagbara nilo iranlowo kiakia.

Bakanna, awon ajo meteeta wonyi ti se aseyori to lapere ninu dida awon arinrinajo pada silu won tabi ilu miran ti aabo wa. Ninu akitiyan won, won ti se iranwo pupo fun awon arinrinajo ti won n dapa naa lati fidimule pada si awujo ilu won.

“Awon igbimon naa ti se aseyori nipase dida awon arinrinajo to ju egberun merindinlogun pada si ilu won lati ilu Libya, bakanna ni awon arinrinajo ti won wa ni awon ibudo ijoba gbogbo ti dinku Jojo lati ogun egberun ninu osukokanla odun to koja 2017 si egberunmeta le irinwo nigba ti mo s’abewo silu Libya ni bii osu meji seyin” Elfadil lo so bee.

Amira tun tesiwaju ninu ororo re wipe, akitiyan nlo lowolowo lati owo awon igbimon to n risi ifimufinle ati aabo ninu ajo ile afirika lati gbenawoju awon ajijagbara ati onisumonmi ni ilu Libya ati agbegbe re to je pe awon ni won n jere goboi ninu idojuko awon arinrinajo.

Ajo agbaye kan to n risi irinkerindo awon arinrinajo tun so Di mimo pe o le ni egberun Lona egberun lona egbeta ati ogun awon arinrinajo ti won wa nilu Libya, ninu eyi ti opolopo ti wa nibe fun aimonye odun.

Oro Aworan: Awon aṣikiri to wa ni idaamu ni Libya.