Egbegberun awon omo Naijiria ni won ti da pada sile lati Libya

Egberunmeje le ni ojileleedegberin ati mefa awon omo orile ede Naijiria ni won ti da pada sile lati orile ede Libya labe akitiyan ajo agbaye to n risi irinajo (IOM) ifinufindo ati ifimonle, eyi ti won n se pelu ifowosowopo ajo isokan ile yoroopu (EU).

Awon eniyan tuntun ti won finnufindo pada wa si orile ede Nigeria laipe yi ni won je ogojolemarun ti won de ni ojo keta osu karun pelu oko ofurufu oniyiya, eyi je pelu iranlowo ajo IOM.

Olori ajo akitiyan IOM ni orile ede Nigeria, Enira Krdzalic, so ekunrere oro na lati ilu eko nigbati ti awon arinrinajo to dari de keyin gunle si orile ede Nigeria.

Gege bi Krdzalic se so, egbeta awon tajode naa ni won ti fi monle, nigbati igba awon tajode miran yo tun di fifimonle.

Ajo osise oniroyin ile Nigeria (NAN) fi rinle wipe okookan awon tajode naa ni won fun ni egberun metadinlogun ati ogorun naira bakanna ni won gbewon de ibudoko Jibowu lati wo oko ile ikookan won.

Krdzalic wa ro ijoba orile ede Nigeria lati tunbo tera mo akitiyan re ninu ipese ise fun awon tajode naa bakanna lo tun tenumon ki ijoba maa se idanileko loore koore fun awon omo Nigeria lori ewu to wa ninu irinajo ti ko b’ofinmu s’ile okeere fun oro aje. Alhaji Mustapha Maihaja, eni to je adari agba fun ajo to n doola isele pajawiri ni Nigeria (NEMA), so pe awon n fowosowopo pelu ajo IOM lati ri daju pe awon omo orile ede Naijiria ti won wa ninu iwariri lati pada sile lati ile Libya di kiko wa sile.

“a wa sibi lati ri daju pe won di gbigba wole pada lona to to. A n fun won l’onje ati owo lati dawon pada si ile won ” o soo di mimo. Adari ajo NEMA ni ibuwo oorun , Mr. Suleiman Yakubu, soro boti se pataki fun awon odo ile Nigeria lati se iranlowo fun idagbasoke orile ede nipase nini irori toto ati diduro sile.

“orisirisi akititiyan ni ijoba towa lode bayi ti se lati ri pe igbe aye rorun ni Nigeria ” o so bee.

Maihaja fi kun oro re pe awon ijoba ipinle, papa julo ijoba ipinle Edo, ti se eto ikoni ati ironilagbara lati fi awon tajode na mule pada Sile. O tun fi kun pe irufe eto na lati owo IOM ni yo gberaso ni osukeje odun yi.

Ajo NAN fi lede gege bi ajo ton risi igbokegbodo awon omo orile ede Nigeria ni orile ede Libya, Mr. Illiya Fachano, se so wipe, ijoba apapo orile ede Nigeria ti da egberunkanleniigba ati metala pada sile ninu abala akoko odun 2018 yi.

Nigbati on fi emi imoore han si akitiyan ijoba apapo orile ede Nigeria bi o se dawon pada sile, awon tojode naa tun rawo ebe s’ijoba fun iranlowo lati gba igbayegbadun won pada.

Orisun Aworun: https://www.dailytrust.com.ng/165-nigerians-repatriated-from-libya.html

TMP – 13/06/2018