Ajo Isokan agbaye UN se itaniloji fun awon afinisowo ni orile ede Libiya

Mefa ninu awon olori itakun afinisowo ni orile ede Libya ni eka eto aabo ninu ajo isokan agbaye ti ta loji bayi. Eleyi ni igba akoko ti awon afinisowo na yo di mimenuba ninu iwe itaniloji ajo na. Merin ninu awon afinisowo ti won ta loji na ni won je omo orile ede Libya nigbati meji toku je omo orile ede Eritrea. Itaniloji naa ni yoo dena ati se irinajo lo si ibikibi fun awon mefeefa na koda, won yoo si gbese le awon dukia won.

Ni awon odun die seyin, orile ede Libya ti di aresepa fun awon oluwo Lona aito ati awon afinisowo, bakanna ni o je ibi ategun fun awon arinrinajo ti won fe wo ile alawo funfun nipase oju omi.

Itaniloji tuntun na lo waye nipa bi ipe se n wole lemonlemon lati awujo agabaye wipe ki ajo gbe igbese to lagbara lori awon afinisowo ile Libya. Orile ede Netherlands ni o koko pe ipe na ni ojo kinni osu karun. Ipe na je ohun ti won gba wole ni bi iroyin kan se fi aworan kan lede t’on s’afihan bi won se n ta awon arinrinajo omo Africa gege bi eru ni odun to koja.

“Ni odun to koja, aworan bi won se n ta awon omo Africa gege bi eru tile yawa lenu pupo, eyi lo mu eka eto aabo lati pinnu pe awon yo se igbese to to,” olubewo omo ile America si ajo isokan agbaye UN, Nikki Haley lo so bee.

“Itaniloji to waye loni ni o n fi idi’e mule pe ifowosowopo to lagbara lowa laarin awujo agbaye lati mojuto ise owo awon afinisowo eru ati amunirinrinajo lona aito. Ko tile si aaye nibikibi lagbaye fun iru iwa ite eto ati aponle omoniyan loju be,” gege bi o se wi.

Okan ninu awon okunrin na, to je omo orile ede Eritrea ti o’oko re nje Ermias Ghermay, ni won ti juwe re ninu iwe ibeere fun itaniloji na gege bi olori itakun to n risi “ifinisowo ati imunirin lona aito fun egbaagbeje egberun awon arinrinajo” lati aarin gbungbun ile africa lo si erekusu ile Libya titi wo ile alawo funfun Europe ati ile Amerika.

Awon yoku ti won taloji ni arakunrin Abd Al Rahman al-Milad, olori alaabo fun erekusu ile Libya to wa ni Zawiya : Mohammed Kachlaf, olori omo ogun oniranlowo , ajijagbara ni Zawiya, iwo oorun ile Libya; Ahmad Oumar Al – Dabbashi, olori Miran fun awon omo ogun ile Libya; Musab Abu-Qarin, bakanna lati ile Libya; ati Fitiwi Abdelrazak lati orile ede Eritrea.

Ni gere ti won kede itaniloji na akowe agba fun ajo isokan agbaye, Antonio Guterres ko lori ero twitter ready pe “o tile bawa lokan je pupo bi a se ri aworan awon eniyan ti won n ta ni orile ede Libya lodun to koja. Mo faramon ipinnu eka eto aabo lati ta awon afinisowo mefa na loji. A nilo lati mojuto oro tite etowomoniyan loju”

Lati Odun 2014 wayi, awon afinisowo ti fi ogbagba gbale ni orile ede Libya nitori awuyewuye ton waye nipa eto oselu ni ile na. Lawon asiko na, egbaagbeje egberun awon arinrinajo ni won ti mu rinna nipase okun Mediterranean pelu bi egbeegberun ti se n padanu emi won ninu irinajo na.

Orisun Aworan: voanews.com. Ajo Isokan La’gbaye, U.N., nigba igbimọ ni New York City, U.S

TMP – 13/06/2018