Awon aṣikiri ndojuko ifiyajeni, ipaniyan, ni’lu Libya – Ajo Isokan Agbaye, UN

Ajo iśokan agbaye (United Nations) ti so di mimo wipe awon aṣikiri ati awon olugbelu ndojuko ewu ijinigbe, ifiyajeni ati ipaniyan lati owo awon ẹgbẹ ologun ni ilu Libya.

Ninu atejade ti won fi sode ni ojo kokanlelogun osu keta, eka tonrisi eto omoniyan ninu ajo isokan agbaye so wipe awon omo Libya ati awọn arinrin-ajo ati aṣikiri maa ndojuko ewu jijinigbe ati fifi pamon lona ti ko ba ofin eto omoniyan mu, papaajulo ewu nla nipasę didi tita “loja eru to gbaju gbaja”.

Ni bi odun die seyin, ilu Libya ti di oju ona fun awon aṣikiri ti ko b’ofinmun ti won fe wo ile alawo funfun (Europe), opolopo eyi ti won ma n dojuko ifipamunni, mimu lona ti ko b’ofinmu, ijinigbe, ifiyajeni, fifi eniyan seru, ibanilopo Lona aito lobinrin nigbamiran, iku.

Akowe ajo agbaye fun eto omo’niyan, Andrew Gilmour, so wipe “idajo ti ko tona ati ipaniyan lai leto je ohun t’ogbajugbaja,” eyi lo so di mimo nigba t’onsoro nibi apejo ajo isokan agbaye ton risi eto omo’niyan.

Gẹgẹ bi Reuters, Gilmour so gbangba wipe “gbogi ninu awon odaran ese nla si eto omoniyan n se bee pelu aibikita rara”.

“Ninu ohun ti oti di lemon lemon ninu ati ayika Benghazi fun odun meji seyin, opolopo oku ti won ni apere ifiyajeni to lagbara ati yiyi ni won n ri loju popona kaakiri”, Gilmour fi rinle.

Lodo tire, Adel Shaltut, eni toje alamojuto pataki fun erongba ile Libya si ajo isokan agbaye ni ilu Geneva, sope: “ilu Libya je oludojuko isoro awon oluwo ti ko b’ofinmun, ohun nikan ni aresepa atipe kolee gbe gbogbo ojuse na. Awon omo ogun wa to nso erekusu ko ni agbara to bee ge lati dojuko akojopo awon odaran ati agbesunmonmi to jafafa naa.

Aworan akaale lati owo ile ise iroyin, CNN, eyi ti won fi sita nipari odun to koja tu asiri bi awon aṣikiri nilu Libya se n di tita gege bi eru ni oja eru to gbaju gbaja nilu naa.