Ajo isokan ile alawo funfun EU n fe ifowosowopo to dara pelu Nigeria lori irinajo s’ile okeere

Ni ojo ayeye kan ti won fi sori “ojo ile alawofunfun ti odun 2018” to waye no abuja, asoju ajo isokan ile alawofunfun to tun lewaju igbimon ile naa si orile ede Nigeria, Ketil Karlsen, soro lori botijepe ifowosowopo laarin ile alawo funfun ati orile ede Nigeria ti le mu ki ajosepo to dan moran to wa nile tele lori oro aatele nipa irinajo, eto aabo oro aje ati eto ijoba awa araawa.

Karlsen ko s’alai menuba “okan o jokan ifowosopo toòto to wa laarin ile alawo funfun EU ati orile ede Nigeria ninu ajose to dara pupo sugbon ti o si nilo lati te siwaju sií”.
Lori oro wiwo ile alawo funfun lona ti ko tona, adari ile alawo funfun na si Nigeria gbarata, o sope “o tile je ohun ibanuje funmi nigbati mo ba ri ipo to buru ti awon omo orile ede Nigeria ma nwa lowo awon afinisowo, opo tile ma n gbemimi ninu asale, bakana opolopo lo ma n dojuko ifiyajeni ninu ipago kereje -kereje nilu Libya, awon kan tile ma n ri sinu okun mediterania atipe awon miran ndojuko idite moni to lagbara ni ile alawo funfun. ”

O tun fi rinle wipe ile alawo funfun ti fi awon omo orile ede Nigeria to to egberunmejo o le ogorunmeje sowo pada sile ni odun 2017 atipe ajo na n fowosowo ni orileede Nigeria fun ona abayo si isoro naa nipase mimu eto igbayegbadun awon odo lokunkundun, ati bibu anu ate lu ifinisowo eru ati iyannije.

“A nilo isokan lati fi opin si isele na. A nilo lati fohun sokan lori ipe ti aare Buhari pe awon alafowosowopo ni ile alawo funfun lojuna ati fi opin si idojuko na, nigbati o n fi ipinle rere lele lati ri dajupe isoro na ko sele mo lojo’waju,” o so pe, lori oro iwolu laibofinmu, olori ile ise aatilo lori oro ile okeere ni Nigeria Geoffrey Onyeama fi bi isoro na se tobi to mule, o so pe ijoba orile Ede Nigeria n se akitiyan lati gba awon omo orile ede Nigeria niyanju ki won o ma se irinajo l’ona to ba ofin mu.

Erongba lati sise papo pelu ajo isokan alawo funfun lati se asoye ati adehun lori bi yoo se rorun lati ma se irinajo wo ile alawofunfun lona to be ofin mu ati lati ko fun awon miran nibi gbigba ona to lewu. Adari na so di mimo pe ijoba orile ede Nigeria ni awon erongba lati pese eto ikose owo ati awon eto idagbasoke miran ti yo mu ki awon odo na le duro sile ti won yo si le kopa to joju ninu idagba some awujo.

Adari ile igbimon asofin agba ni orile ede Nigeria, ogbeni Bukola Saraki so pe ile igbimo asofin na ti gbaa lero lati Lo eto ofin sise lati tunbo ro ajo to n risi didena ifinisowo eru lorile ede Nigeria (NAPTIP) lojuna ati fun igbese ayewo awon oluwo ti ko b’ofinmu lati ipinle lagbara si yato si sise ayewo na ni enu bode awon ilu miran.

 

Ketil Karlsen nigba ti a soro. Ni owo eyin ni are igbemu asofin, Bukola Saraki ati iyawo re pelu Mrs Karlsen. ORISUN AWORAN: Premiumtimesng.com

 

TMP – 07/06/2018