Eyi ni ijamba ọkọ oju-omi ti o buru ju lori okun Mẹditarenia ni ọdun 2020

O to marundinladọta awọn aṣikiri ti n lọ si Yuroopu, ni o ti ku ninu ninu jamba ọkọ oju-omi lori okun Mẹditarenia ni etikun Libya, ajọ UNHCR lo sọ be. Awọn ọmọde marun wa ninu wọn.

Awọn arinrin-ajo naa wa laarin ọgọrin ti o wa ninu ọkọ oju-omi nigbati ẹnjin bu gbamu, etiyi ti o fa ijamba naa. Wọn ti pe ijamba naa ni ijamba ọkọ oju-omi ti o buru ju ni aringbungbun okun Mẹditarenia ni ọdun 2020

Awọn metadilogoji ti o ye ijamba naa ni o jabọ iroyin naa. Awọn apeja lo gba wọn la, eyiti pupọ wọn wa lati Ghana, Mali, Chad, ati Senegal. Wọn ti mu awọn ti o ye sinu atimole bi wọn shey de si Libya.

TMP_ 21/08/2020

Orisun Aworan: Shutterstock/Alexandros Michailidis

Akori Aworan: Aṣọ igbala ti a fi silẹ nipasẹ awọn asasala lori eti okun ti Skala Sikamineas