Akitiyan Naijiria lati dopin irinajo aibofinmu
Orile ede Naijiria ti jinle ninu wiwo ilu okere ni ona ti ko bofinmu. Ti oro ba d’oro ka wo ilu lia bikita kaakiri agbaye orile ede Naijiria je okan gbogi.
Eyi je ohun itiju fun orile ede na debi wipé opo awon omo orile ede Naijiria to je onisowo n dojuko ipenija to lagbara ni awon ilu okeére, koda ni afirika paapa. Eyi ribee nitoripe awon omo orile ede Naijiria to fe soda si ile alawofunfun lona aito n po si lojoojumo. Nibamu si isele yii, ijoba apapo orile ede Naijiria ti gbe igbimo kan dide lati maa risi igbokegbodo nipa irin ajo lona aito ati fifiniśowo eru ni orile ede Naijiria.
Igbimo naa eyi ti oga agba nile ise iwole-wode, ogbeni Mohammed Babandede ati eni toje adajo agba ati komisona fun eto idajo ni ipinle Edo, ojogbon Yinka Omoregbe n solori fun ni ijoba ti paa ni dandan fun lati wa ona kan gbogi ti yoo fopin si wiwo ilu lona aito ati fifini sowo eru.
Igbimo naa ni alakoso abenu, Lt. General Abdurahman Dambazau (toti feyinti), fi lole to si paa ni dandan fun igbimon naa lati fi oju sununkun wo gbogbo awitunwi lori iwolu laibofinmu ati fifinisowo. “e ma se gbagbe wipe orile ede Naijiria je aresepa, botilejepe awon omo orile ede yi n wolu okeere lai bofinmu, gege bee ni awon oluwo laibifinmu n wo orile ede Yi.” o so fun awon igbimo naa.
“Mo n ro yin lati f’oju sununkun wo oro naa, bi a se le dawon lekun, paapajulo ni bi o se kan ipinle edo gbangban, nitoripe pupo ninu awon afinisowo naa lo wa lati ipinle na gege bi iwadi se fin rinle. ” o fikun oro re.
“Koda ko duro lori ifinisiwo lojupannan okun pupa nikan, ifininsowo na tawe-tagbo lorile ede yi, agbegbe yi ati ni orile yii. ” alakoso naa fi rinle.
Ajo ti ko rogboku le ijoba to wa ni ilu Gusau, so wipe bi aba le wa ohun kan gbogi to n mu ki awon eniyan maa gun le irinajo lona aito lorile ede Naijiria ni yoo je ona abayo kan soso si isoro naa. Ajo na so wipe asiko tito lati se atunse to loòrin si adisokan ati erongba awon omo Naijiria ti won ro wipe anfaani orisirisi lopolopo lowa nilu okeere nipa lilo awon ero igbohun s’afefe wa gbogbo.
“Ile ise akoso to n risi oro ile okeere gege bi ose je wipe ohun lon siwaju ninu oro ile okeere gbodo fi ara re jin gidigidi lori oro to nii se pelu igbokegbodo, bakanna ni o gbodo maa sise papo pelu awon awujo agbaye.” ajo Gusau so eleyi ninu abajade iwadi won leyin isori ijoko eleekeji ti o se pelu ajo GI.
Abajade iwadi ajo Gusau na so di mimon wipe ti a ba lee mu ki oro aje ilu dagba soke daada eyi yoo je ona abayo to loorin si isoro wiwo ilu laibofinmu ni orile ede Naijiria, botilejepe igbese yi nilo ki awon ajo t’orokan gbodo fowosowopo. Lati se eyi, o se pataki ki awon ajo naa maa se alabapin awon ifitonileti to se pataki ti a ba feran lati pinwo awon odaran paali ati awon afini sowo nibi ise buruku owo won.”
Atejade naa tun so di mimon si wipe “lori ona ti awon arinrinajo lona aito n rin lojuna ilu Niger, oludari ile ise akoso abenu gbodo so asoyepo pelu awon ijoba orile ede to paala pelu orile ede Naijiria Lori ona ti a le gba lati f’opin si awon arinrinajo ti ko to lojuna orile ede Niger.”
“Dida pada sile ati fifi mole awon arinrinajo lona aito lo gbodo je ohun ti a dijo mojuto lona ti yo mu awon eniyan naa lati fe pada sile fun ki won si bere igbesi aye won lakotun pelu iyi, eye, ati aponle.” iwadi ajo GI fi rinle.
Orisun Aworan: senatepresident.gov.ng. Akitiyan ijoba Naijiria pelu ajo Yuroopu (EU) lati dopin irinajo aibofinmu
TMP – 28/05/2018
Forukọsilẹ fun awọn otitọ isilo
Pin akole yii