Irin-ajo alaibamu si Yuroopu dinku si kekere julo lati ọdun 2013

Apapọ arinrin-ajo 127,657 ni o wọ Yuroopu ni ona alaibamu ni ọdun 2019, eyi ti o tunmo si pe irin-ajo alaibamu si Yuroopu wa si nọmba ti o kere julọ lati ọdun 2013.

Nọmba naa, ti ajo International Organization for Migration (IOM) gbejade, se afihun pe 103,883 awọn eniyan ni o wa nipasẹ okun ati 23,774 nipasẹ ilẹ. Afiwe si ọdun ti tẹlẹ, se afihan pe awon ti o de nipase okun ati ilẹ ti dinku nibi ipa mejila ninu ogorun.

Orile-ede Greece gba ọpọlọpọ awọn arinrin-ajo to nwọle, eyiti o to 70,000 awọn arinrin-ajo titun. Ilu Spain ni o je ikeji, pẹlu awọn olugba 32,531, ti Italia tẹle pẹlu 11,471.

O to awọn eniyan 1,283 ni o ku ni ọdun 2019 ni igbiyanju lati de Yuroopu nipasẹ okun Mẹditarenia. Ni ọdun 2018, nọmba naa jẹ 2,299. Lati ọdun 2014, ni gbogbo ọdun o ma n ju awọn 1,000 ti o n ku ninu okun Mẹditarenia, o si ti koja iku 19,000 ni ọdun mẹfa to kọja lọ.

Ọna aringbungbun Mẹditarenia (si Malta ati Italia) tẹsiwaju lati jẹ eyi to buru julọ fun iku. Awọn oniwadi lati eto Missing Migrants ṣe iṣiro pe ọkan ninu eniyan metalelogbon ku ni igbiyanju lati lo ipa-ọna yii ni ọdun 2019, ni afiwe si ọkan ninu marun-din-logoji ni odun 2018 ati ọkan ninu aadọta ni odun 2017.

Oludari ti Ile-iṣẹ Iwadi Iṣeduro ti IOM Frank Laczko sọ pe: “Won lẹ ma ri oku awọn ti o sọnu ni okun ni ọdun yii rara, bii ẹgbẹẹgbẹrun awọn miiran ti o sọnu ni Mẹditarenia. Ni ọdun kọọkan ti awọn iku wọnyi tẹsiwaju tumọ si awọn idile diẹ sii n gbe ninu iporuru, lai mọ boya ibatan kan ti ku tabi laaye.”

O fikun: “Ti o ba wa lati orilẹ-ede ti n ni oro-aje ti o da, a o sa ipa lati wa ati lati ṣe idanimọ ara rẹ ti o ba padanu. Eyi kin n se fun awon arinrin-ajo ti ko ba ni iwe irin-ajo.”

TMP – 16/01/2020

Orisun Aworan: Malcolm P Chapman / Shutterstock

Akori Aworan: LESVOS, GREECE SEPTEMBER 24, 2015: Ọkọ oju-omi roba kekere ti awọn arinrin-ajo n lo lati rekọja okun lati Tọki ni eti okun nitosi Molyvos. Lesbos ti di aaye ti o gbona fun awọn arinrin-ajo si Yuroopu.