Orile ede Hungari ti se ofin ti yo ma so awon oluranlowo ati agbodegba awon oluwo ti ko b’ofinmu di odaran

Ni ogunjo osu kefa odun yi, ile asofin ti orile ede olominira Hungari so awon aba kan ti yo ma so enikeni tabi ajo k’ajo to ba n se iranlowo tabi atileyin olookan fun awon arinrinajo alaibamu ati  oluwo ti ko k’obofinmu di odaran ni orile ede na.

Awon aba na ti ijoba orile ede Hungari pe ni “e da soro duro ” eyi ti won fi sori ajaf’eto omoniyan ati olutore anu kan ti oruko re n je  George Soros, eni ti ijoba orile ede Hungari ti fi esun kan wipe o n se alatileyin fun awon arinrinajo elesin musulumi – fi aaye gba ijoba lati ju enikeni yala,  aladani tabi awon ajo ti ko rogboku le ijoba (NGOs) ti won ba kefin pe o n se alatileyin ati oluranlowo fun awon arinrinajo ti ijoba ko fiwe le si ewon, Ile ise iroyin BBC lo fi lede.

Atunse miran ti won se si ofin orike ede Hungari tun fi mule pe okanojokan ejo nipa awon arinrinajo ni won tile le gbo tabi yanju ni orile ede na na mon,  eleyi je atako ponbele si ofin alajose ile Europu, ori kokandinlogoji ofin na tun se apatenujewo igbimoran lati si awon arinrinajo ti won to egberun l’ona ogorun kan ati aadota awon omo orile ede Eritrea, Syria, ati Iraq ti won fe atipo ni awon Ile alawofunfun EU nipo pada.

Aba na ti n dojuko ibenuate lu lawujo agbaye ati atako to loorin lati odo awon ajafeto omoniyan kaakiri ile alawo funfun,  awon ajo bi igbimo ile alawo funfun, ajo alaabo ati ifowosowopo ni ile alawo funfun (OSCE) ati ajo iseraeni lagbaye. Iroyin to n jade lati owo ile ise iroyin BBC so pe,  igbimo to n risi oro awon ogunlende ninu ajo isokan agbaye UN tile ro ijoba orile ede Hungari lati jawo ninu ofin to n gbero na. Bakanna ni awon ojinni amofin ninu igbimo ile alawo funfun ti s’apejuwe ofin tuntun na gege bi “ofin ida konko” ofin to ruju, ati ofin to fi gbogbo ara tako ofin alajumose ile Europu.

Ibo ti won di ni olu ilu orile ede Hungari na ni o waye siwaju iforojewo nipa awon isele to waye laarin awon asiwaju ajo Ile alawo funfun lori bi won yo se se atunse si eto atipo sise.  BBC lo jabo bee.

Orile ede Hungari so pe awon oluwo n fi ewu wu eto aabo ile na.  Eni tii se oludari fun ile ise abenu fun ile na Sandor Pinter, so pe awon eeyan orile ede Hungari tile n s’agbiyele lati odo ijoba orile ede na lati lo gbogbo Agbara to wa ni ikawo re ninu gbigbogun ti wiwo ilu na lai b’ofinmu ati awon ohun to n se okunfa re, Guardian lo do di mimo be.

Awon aba “e fopin si soro ” na ni a lo lati fun mun agbiyele na wa si imuse, eyi lo so awon akojopo arinrinajo lai bofimu di odaran  ponbele ” Pinter fi mule. “a lo abadofin na lati pinwo siso orile ede Hungari di ibufarasin fun awon arinrinajo lai b’ofinmu,” o fi kun oro re.

Oro awon arinrinajo ti ko b’ofinmu ti di wahala kan gbogi fun awon oludibo kaakiri ile alawofunfun, ninu eyi ti won ti jumo fi ijoba to lodi si iwolu lona aito je ni orile ede Italy ati Austria ati bi won se n dun’kooko lati ba ajosepo olosu meta to wa laarin Merkel ati orile ede Gamani je.

TMP – 28/06/2018