Wọn gba Jẹmani ni imọran lati ṣeto owo fun fisa fun awọn arinrinajo lati Afirika  

O yẹ ki Jẹmani ṣeto ilana iwe iwọlu nipasẹ eyiti ti awọn arinrinajo Ilu Afirika le gba ni iwe iṣẹ igba diẹ pẹlu idogo owo, beni igbimọ Expert Council of German Foundations on Integration and Migration (SVR) ṣe sọ. Awọn amoye sọ pe eto yii yoo ṣe idinku fun irinajo alaibamu beni yoo tun ṣe iwuri fun ipadabọ ti awọn arinrinajo nigba ti fisa wọn tọn.

Eto imulo ti wọn gbero naa yoo gba awọn arinrinajo lati Afirika laaye lati ṣiṣẹ ni igba diẹ ni Jamini, ki wọn bale fi owo pamọ, ati gba awọn ọgbọn ti wọn le lo nigbamiran ni awọn orilẹ-ede wọn. O yoo tun ṣe iwuri fun awọn arinrinajo lati pada si awọn orilẹ-ede wọn ni ipari awọn iwe iwọlu wọn lori eyiti wọn yoo da idogo owo wọn pada.

Igbimọ naa rọ Jamini ati awọn orilẹ-ede EU miiran lati ṣawari awọn ọna tuntun lati ṣiṣẹ pẹlu awọn orilẹ-ede Afirika lori ọrọ irinajo.

TMP_ 04/05/2020

Orisun Aworan: Shutterstock/vanhurck

Akori Aworan: Iwe irin-ede Amẹrika pẹlu iwe irinna ilu Yuroopu