Libya: Awọn aṣikiri ti o koja aadọrin rì ninu igbiyanju lati de Yuroopu    

Awọn aṣikiri mẹrinlelaadọrin rì ni ọsẹ ti o kọja nigbati ọkọ oju-omi kekere kan ti o lọ si Yuroopu ṣubu ni etikun Libya. Ajalu yii jẹ ikẹjọ iru e lori ọna yii lati ibẹrẹ Oṣu Kẹwa, ajọ International Organisation for Migration (IOM) lo sọ bẹ.

Awọn arinrin-ajo ẹtadinladọta nikan ni ẹṣọ etikun Libyan ati awọn apeja agbegbe na ri gbala. Oku awọn mọkanlelọgbọn ni a gba pada lati inu okun, ati wiwa naa tẹsiwaju fun iyoku ti awọn arinrin ajo ti o padanu.

Pipadanu emi lori Mẹditarenia sẹ ifihan pe awọn orile-ede ko ṣe ipinnu  lati mu ilano irin-ajo ti o da, iwadi ati igbala” Federico Soda, IOM Libya Chief of Mission sọ .

O kere ju eniyan 20,000 ti ku ni Central Mẹditarenia lati ọdun 2014.

TMP_13/11/2020

Orisun Aworan: Shutterstock/Max Lindenthaler

Akori Aworan: Jaketi aye ti n lefo ori omi