Ile geesi ati Naijiria yo fowosowopo gbogun ti irinajo lona aito ati ifinisowo

Ijoba ile geesi ti so di mimo pe ohun yo kun orile ede Nigeria lowo ninu akitiyan re ninu gbigbogunti ati fi fi iya je awon afinisowo ati awon agbodegba won ni orile ede Nigeria ati oke okun, eyi wa ni ibamu si atejade ti iwe iroyin vanguard gbe Jade.

Laure Beaufils, igbakeji asoju ile geesi si orile ede Nigeria, so pe atileyin ijoba ile geesi fun ijoba orile ede Nigeria lori akitiyan re lati pinwo anfinisowo duro digbi, o so eyi nibi akanse agbekale kan to da lori ifowosowopo laarin ijoba orile ede Nigeria ati ile geesi lati wa ojutu si isoro to ro mon irinajo lona aito.

Beaufils so pe, “awon osise agbofinro wa gbogbo ni ajosepo olojopipe to gunmon to si s’esorere pelu awon alabasise po won ni orile ede Nigeria : ajo to n risi iwa odaran ati ajo arinrinajo lagbaye ni won ti n sise papo pelu ajo orile ede to n risi igbogun ti ifinisowo (NAPTIP), lati bi odun die seyin lati fi iya to to je awon afurasi afinisowo. Atipe a n wo awon ona lati lekun atileyin na fun orile ede Nigeria.

Adari gbogboogbo fun ajo NAPTIP, Julie Okah – Donli, dupe pupo lowo ijoba ile geesi fun atileyin re lati gbogun ti iwa anfinisowo.

Beaufils to menuba ifarajin alakoso agba fun ile geesi Theresa May ninu akitiyan re lati wa ni ipo iwaju ninu fi fopinsi owo eru igbalode ati iwa ifinisowo bakanna ni o tun tenumon bi ose se pataki ki won fi owo sowopo pelu awon oko owo, aladani ati awon ile ise ijoba.

Theresa May ti n gba “ojuna ofin ati itele re” lati gbogun ti ifini sowo sugbon ijoba re ti fi erongba won han si ojuna miran to lagbara ti yo se alajoro pelu awon oko owo lati pinwo ifipa muni sise bakanna ti yo si se won lakin lati ma sise l’ona gbefe yato si ona ifipa muni.

TMP – 18/07/2018

Awọn oniṣowo ni ipinle Gusu orile ede Naijiria, Edo ti wa ni ifojusi awọn obirin, awọn ọmọbirin ati awọn ọmọkunrin lati awọn agbegbe ipalara.

Aya Aworan:Elena Perlino/REX/Shutterstock