Ajo NAPTIP n fe lati ma f’ofin mu awon afinisowo l’awon bode

Ajo orile ede Nigeria to n gbogun ti ifiniyan sowo, ajo orile ede to n dena ifinisowo (NAPTIP), ti pe fun ifofinmu ati ifiyaje labe ofin fun awon awon afinisowo nile okeere kaakiri agbaye.

Adari agba ajo na, Mrs. Julie Okah-Donli, lo pe ipe na laipeyi nigba ti o n gba alejo awon olubewo lati ilese asoju orile ede Spain towa ni Abuja. Gege bi adari na se so, ise owo awon afinisowo nile okeere na ni o n pagidina okanojokan akitiyan ajo agbaye ti o n polongo tako iwa ifinisowo.

Okah Dinli wa tokasi fun awon omo egbe ajo isokan ile alawofunfun ati awon ajo agbaye miran lati pese ati se awari ogbon atinuda lori isowosise ati agbegbe ti awon afinisowo na pago si ni orile ede Nigeria, ki ajo NAPTIP le fi ofin muwon ati fi Iya to to jewon labe ofin.

O so fun awon alejo na pe mimu awon afinisowo ti won pago si ile alawofunfun ni yio je aseyori kan gbogi fun eto igbogunti ifinisowo na.

“Fifi ofin mu ati fifi iya je labe ofin awon afinisowo ti won farasin si awon ile alawofunfun ni o se pataki si awon akitiyan wa lati f’opinsi iwa ifinisowo ni orile ede Nigeria.

A ro yin lati fi owosowopo pelu wa lori sise alabapin iroyin lori erongba lati tu asiri awon afinisowo abileko na ti won fi ile okeere se’bugbe, ninu eyi ti a ni igbagbo pe won wa leyin bi won se n lo awon odo wa nilokulo.

“A fe ki etu asiri won ki won o si foju ko ata ofin. Eyi ni okan ninu awon ona ti o le fun wa ni aseyori lori awon igbogun ti ifinisowo na, ” o fi kun oro re.

Alori awon igbimo olubewo Spain na so pe. Igbimon na se abewo si ajo NAPTIP lati se alaye ni ranpe fun awon adari won lori eto owo ikokanla iru re ti o je ti idagbasoke ile alawofunfun, eyi ti won fi sori igbogunti iwa ifinisowo ni orile ede yi.

Erongba kan gbogi ti idawo na ni, ni lati din ifinisowo ati imunirin lona ti ko to ku jojo, laarin orile ede Nigeria ati ile alawofunfun, paapajulo ajo na yo dajuso awon obinrin ati awon omode.

TMP – 14/08/2018

Orisun Aworan: www.naija.ng. Awọn onisowo iṣowo eniyan ti wọn mu nipasẹ NAPTIP