Awon tajode n fi’di mule pada ni Orile ede Nigeria
Egbaagbeje awon omo orile ede Nigeria ti won fi sowo pada sile lati orile ede Libya leyin ti won ti padanu ninu igbiyanju won lati fo okun koja losi ile alawo funfun ni won n gba idanileko ati idurotini lojuna ati le fi’di mule pada sile ninu isesi, ihuwasi ati ikopa lawujo si awujo orile ede Nigeria.
Leyin igba ti won ti fojuwina idojuko olokanojokan ninu asale, ilu Libya ati opolopo awon ilu miran, won nilo lati se atunto igbesi aye won ki won le wulo ati ko ipa tiwon si idagba soke awujo orile ede Nigeria.
Nilu Libya, opolopo awon arinrinajo ni won gba idojuti nitoripe won lowo ninu tita ati rira nkan ogun, oogun oloro, ole jija ati ise asewo. Koda, awon kan ninu awon tajode naa ni won n lo bi eru ki won to dawon pada si orile ede Nigeria.
Okanojokan iriri ti awon tajode wonyi ti ri ko han loju won, idi niyi ti o idanileko na fi gbodo je yajoyajo. Ireti wa pe leyin akitiyan na, awon tajode na yo ma ri ara won gege bi irinse idagbasoke ati ayipada. Idanileko na ni yo je okan pataki ti yo ma dena ati b’enu ate lu irinajo lai gba ojuponna ofin.
Gege bi Osita Osemene, eni t’oje asiwaju fun eto idanileko to n lo lowo lowo fun awon tajode omo orile ede Nigeria, o le ni eedegberin awon tajode to won ti j’anfaani ninu itaniloji ati idanileko na seyin. Eto na ni ajo isokan ile alawo funfun ati ajo to n risi igbokegbodo awon arinrinajo lagbaye (IOM) ajo to n daabo bo awon arinrinajo dijo se eyi ti ijoba apapo orile ede Nigeria n se amojuto re, nipase ajo to n risi awon olufiwo, arinrinajo ati awon ogunlende labele.
Erongba kan gbogi ti idanileko yi ni gege bi Osemene se so, ni lati fi okan awon tajode na bale ati mule pada si awujo ati lati pese anfani alailegbe fun won. Igbese yi yo mu ki awon ti won ba yan yo ninu idanileko na lati le se atunse si eto igbesi aye won.
Nibamu si oro ti osemene so, awon ti won ba ti se aseyori lori eto na ni oruko won yo wo iwe nibamu si iru ise owo ti won le maa se ninu eyi ti a o si ta won loji. Olori olawon oludanileko na lo so be. ” a tile ma n pin won si isori nibamu si eto eko ise ti won ba n ko, awon ise owo bi ajorinmonrin, onidiri, kanlekanke, pejapeja, kata-Kara ati bee bee lo.”
Osemene tun te siwaju pe eeyan meta si marun ni won ma n wa ninu isori kookan atipe ni gere ti won ba ti le pese awon iwe idanimo bi iwe owona, iwe idanimo omo orile ede, ile itaja tabi ile, otile le jepe iwe ijeri si rira awon irinse ti won nilo fun oko owo, ni IOM yoo san owo na ni kikun fun olutaja na, ti olutaja na yo si ko awon irinse na funwon ni kiakia.
Awon ajo ayanilowo sowo, nipase ajo ijoba apapo to n risi eto ifiniwo arinrinajo ati awon ogunlende labele ni yo ma se amojuto awon tajode na lati ri daju pe eyikeyi okowo ti awon tojode na ba dawole ni won kogoja lori re.
TMP – 06/06/2018
Forukọsilẹ fun awọn otitọ isilo
Pin akole yii