Egbeegberun awon arinrinajo omo orile ede Nigeria ni won fi’pa mu sise asewo ni orile ede Italy

Egbeegberun awon omo orile ede Nigeria ni won fi ipa mu lati se ise asewo lodoodun ni orile ede Italy, eni ti o je adari agba fun ajo isedale to n gbogun ti iwa ifinisowo  (NAPTIP), Dame Julie Okah-Donli lo fi idi re mule bee.

Adari agba ajo NAPTIP na ni o lo idi ounka na mon abajade iwadi ti ojo ajo to n risi iwolewode lagbaye se nigba ti o n se idanileko kan ti won pe ni ” sise irinajo lopo yanturu ati idagbasoke orile ede : atupale irinajo sise larin orile ede Nigeria-Libya ati ile alawofunfun bi o se n sele lowolowo ” eyi  ti o se nibi ayeye kan ni ipinle Delta, ni orile ede Nigeria.

Okah-Donli tile laa monle pe awon arinrinajo ti won n dojuko ijeninipa sise asewo na ni won je awon ti awon eniyankan fi sowo eru de orile ede na atipe ipinle edo, kano ati Delta ni awon ipinle to n lewaju ninu irinajo ifinisowo lati orile ede Nigeria.

“Ipinle Delta ni o wa ni ipoketa ninu awon ipinle to n dojuko isoro na ti o si tele ipinle Edo ati Kano lapapo. Ojuse lati daabo bo awon omo wa nibi ifinisowo eru ati irinajo ti ko b’ofinmu ni o je ti gbogbowa: a gbodo ji giri lati se atileyin fun awon agbekale ati akitiyan ti won n se lati daabo no orile ede wa.”

Gomina ipinle Delta, Dr. Ifeanyi Okowa,  tile wa nibi apejo na atipe o fi aidunun re han si bi o se je pe ipinle re na wa ni ipo keta ninu awon ipinle ti irinajo ti ko b’ofinmun ati ifiniowo ti wopo julo ni orile ede Nigeria.

O wa pe fun ifowosowopo akitiyan lati le f’opinsi irinajo tikotona ati ifinisowo ni ipinle na “a ni lati fowosowo ati sise papo ki a le f’opinsi si iwa ifinisowo ni orile ede Nigeria. Bawo ni eniyankan yio se na owo to po lati  se irinajo lo si ibudo ogun ni orile ede Libya tabi Mali? O bani ninu je pe opolopo awon eniyan ti won fi sowo s’ile okeere na ni won ko mon ibi pato ti won n lo lododo, koda won tile n ko awon miran lo sile okeere lati lo pawon ki won o si yo awon eya ara won lati fi se ogun owo.”

Okah -Donli tile tenumon bi o se se pataki fun awon obi ati awon miran ti oro na kan lati f’owosowopo pelu akitiyan ijoba ninu erongba re lati wa egbo dekun fun iwa anfinisowo sile okeere ati irinajo ti ko b’ofinmun nipa bibu enu ate lu iru irinajo bee nigbakigba ti awon odo orile ede Nigeria ba n gbiyanju lati gun le iru irinajo be.

TMP – 06/09/2018

Orisun Awon: www.pulse.ng. Omo Naijiria to n se asewo ni Italy.