Ọpọlọpọ awọn ọmọ orile-ede Naijiria n fi emi won wewu nipa ṣiṣe igbiyanju lati rinrinajo alaibamu si Europe nipasẹ Libiya, pelu iran aṣeyọri. Nitootọ, mẹsun ninu mewa awọn arinrinajo lati Naijiria n reti lati ri iṣẹ se laarin osu mẹrin ti won ba de si Europe. Ni otitọ, irinajo alaibamu lati Nigeria si Yuroopu jẹ oun ti o lewu.
Ni opo igba, awọn ọmọ Nigeria ko kin le de awọn orile ede to wọn pinu lati lo. Ọpọlọpọ ni lati pada si ipo ti o buru ju bi wọn se lọ. Ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn rin irin ajo nipasẹ Sahara lo si ilu Libya ti ri tabi je alabapin ipaniyan, ijinigbe, idaduro, ifipamuni ati nina. Awọn ti o ba papa de Europe maa ni idapada nitori wọn ko ni ẹtọ ti ofin lati duro.
Oju-awe ayelujara yii n ṣe akojọpọ awọn alaye ati imoran ti o ni gbẹkẹle ni gbogbo asiko lori irinajo alaibamu lati orile-ede Naijiria si Europe: iye owo, awọn ewu, ilana isinmi (asylum), awọn ọna ofin ati awọn ona miiran ni a wa ni arowoto. O ni ete lati ṣe iranlọwọ fun awọn ọmọ orile-ede Naijiria lati ṣe ipinnu nipa ipinnu iṣoro ti iṣowo si Europe.