Awon Arinrinajo Si Yuroopu Ndojuko Ewu To Lagbara
Atejade titun lati owo ajo UNHCR ti fihan wipe ewu ti awon arinrinajo ndojuko nigba ti won ban rin irinajo ti ko tona si ofin si Yuroopu ti po si. Eka to rin si irinajo lori omi okun Mediterranean lo se atejade yi laarin osu kinin si osu keta odun yi.
Nibamu si atejade naa, ounka awon arinrinajo ton fi pa wo ilu olominira Itali lati ile Libya dinku niwon ida kerinleniaadorin ninu osuketa akoko odun yii yato si onka won ni odun to koja. Botilejepe onka awon eniyan to padanu emi won loju ona nlekun sii.
Laarin osu kinin ati iketa odun yi, eyan kan nku laarin eniyan merinla nigbati won ba n gbiyanju lati rekoja omi okun Mediterranean, ti aba gbelewon pelu bi eniyan kan se n ku laarin eniyan mokandinlogbon ni osu kinnin si iketa odun to koja. Bakanna ni ounka iye awon ton padanu emiwon ninu awon to n gbiyanju lati rekoja nipase ilu Morocco ati Algeria si ilu Spain ti lekun lonkan jojo laarin asiko kan na.
“Irinajo lati wo tabi laarin ilu Yuroopu fun awon ogunlende ati awon oluwo lo je eyi ti o lewu gidigidi”. Pascale Moreau, eni ti o je adari fun ajo UNHCR to n mojuto ile alawo funfun lo sobé nigba ti o n fi ifitonileti naà lede ni ojokokanla osu kerin.
Nibamu sì atejade naa, ipo ti Libya ati oju ona irinajo na wa n buru si. Opo awon to kogoja wo ilu Yuroopu ni won ti di alaàre, ti won yo si ru atipe ipo ilera won yoo buru jojo. Opolopo ninu won ni won dojuko ifinisowo eru, ifiyajeni ifipa banilopo ati awon iwa ika miran nigbati won ba n wo oko oju omi ni ilu Libya.
Awon arinrinajo ti won ma n gbiyanju lati gba ojuna omi okun Mediterranean koja sile Yuroopo ma n dojuko ewu titeri sinu agbami nipase kikunju oko ojuomi won eyi ti won ma n lo lopolopo igba lati ko awon eniyan to po ju agbara re Lo.
Atejade na tesiwaju ninu agbejade re wipe awon ti won ba gba ojuna omi naa lo si ilu Italy lo wopò lati fojurinju pelu awon eleto aabo ile Libya ti won n so erekusu to si je wipe awon eleto aabo na ti se amugboòro ise won lati inu osu keje odun 2017. Awon arinrinajo ti awon eso alaabo wonyi ba gbamu ni won yoo di mimu pada sile Libya nibiti won yoo ti fiwon pamon si ibi to buru jae titi ti won yoo fi fiwon sowo pada s’orile ede baba won.
Awon arinrinajo ati ogunlende bakanna n fi ara da asilo eni ati irenije lati owo awon afinisowo tabi awon adiha mora lawon ojuna si ilu Yuroopu ninu eyi ti iroyin fi towa leti pe awon afinisowo naa n beere fun owo toto egberun mewa dola lowo arinrinajo ki won o gbee wo ile Yuroopu.
Nilu Yuroopu lohun, orisirisi aato to n sediwo fun oluwo ni won ti gbekale eyi ti o n my awon oluwo lati gba ona ti ko b’ofinmu to si lewu pupo lati de ilu naa.
Atejade na tun so di mimo wipe awon abileko ati odomobinrin, bakanna awon osooro olomokunrin ati odomokunrin paapajulo eyikeyi to ba n darin ninu won tabi adomode ti ko ni alamojuto lori irin ajo re ni won ma n dojuko isele ifipabanilo tabi ifipa muni loju ona won ati ni awon aaye kookan ni’lu alawofunfun.
Siwaju si, nigbati awon omode ba ti wo ilu Yuroopu, fifa akoko gun lati f’oruko sile fun atipo, fififale lati darapo mo awon ebi ati ore ati ai lominira tótó lati tedo je gbogi ninu idojuko naa gegebi atejade ifitonileti na ti so.
O kere tan, o ti to okanleleedegbeta eniyan ti won ti ku tabi di awati nigba ti won n gbiyanju lati se irinajo wo ilu Yuroopu lati gba ti odun 2018 ti bere.
Eni ni Aworan: UNICEF/Georgiev. Obinrin arinrinajo pelu awon omo re meji rin lori reluwe to so Greece paapo pelu Yugoslav Republic of Macedonia.
Forukọsilẹ fun awọn otitọ isilo
Pin akole yii