Awọn aṣikiri ti o ni iṣoro lori okun ti bọlẹ ni Italy  

Lẹhin ọpọlọpọ ọjọ lori okun Mẹditarenia, Italy ti gba ki awọn aṣikiri 180 bọlẹ si ibudo Sicili lati inu ọkọ oju-omi igbala ti Ocean Vikings. Arundinlogbon awọn ọmọde, obinrin meji, pẹlu ọkan ti o loyun ni o wa laarin ẹgbẹ awọn aṣikiri  naa.

Awọn aṣikiri, ti o sa kuro ninu Libya nipasẹ okun, ni ọkọ Ocean Viking gbala ni awọn iṣẹ oriṣiriṣi mẹrin laarin June 25 si 30. Awọn aṣikiri ti ọpọlọpọ wa lati Nigeria, Pakistan ati Eritrea ni wọn yoo mu lo si ọkọ oju-omi ti ijọba ni Sicily lati ya wọn sọtọ fun ọjọ́ mẹrinla nitori arun coronavirus.

TMP_ 08_07_2020

Orisun Aworan: Shutterstock/Stefano Garau

Akori Aworan: Ọkọ oju-omi aṣikiri ti de si ibudo ọkọ oju omi kan ni Ilu Italia lati okun Mẹditarenia.