Naijiria: Ipinle Eko ṣe idasile ẹgbẹ agbofinro lori ifipa gbeni rinrin-ajo

Ninu igbiyanju lati dẹkun iwaa ifipa gbeni rinrin-ajo (human trafficking) ni Ipinle Eko, Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ṣagbekalẹ Ẹgbẹ Agbofinro ti Ipinle Eko lori ifipa gbeni rinrin-ajo. Ẹgbẹ Agbofinro naa yoo ṣe agbekalẹ awọn imọran ati ilana imulo lati le koju iwaa buruku ti ifipa gbeni rinrin-ajo ni ati lati ipinle naa.

Bii 2,884 eniyan lati Ipinle Eko ni a ti gbasile lọwọ awọn afipa gbeni rinrin-ajo ni bi ọdun metadilogun sẹhin, eyi ni oun ti Oludari Gbogbogbo ti National Agency for Prohibition of Trafficking in Persons (NAPTIP), Dame Julie Okah-Donli sọ ni ọjọ keja Oṣu Kẹsan lakoko igbasilẹ ẹgbẹ agbofinro.

TMP_ 10/09/2020

Orisun Aworan: LASG

Akori Aworan: Gomina Ipinle Eko, Mr Babajide Sanwo-Olu, lẹgbẹẹ nipasẹ awọn oṣiṣẹ Ipinle ati awọn ọmọ ẹgbẹ Agbofinro Eko tuntun ti o ṣẹṣẹ bẹrẹ lori gbigbe kakiri eniyan.