Awọn oludari Afirika gbọdọ koju irin-ajo alaibamu, ajọ JIFORM lo sọ eyi
Awọn adari ile Afirika gbọdọ koju idi aini ati oṣi ti o fa irin-ajo alaibamu, eyi ni ajọ Journalists International Forum for Migration (JIFORM) sọ ni apejọ ipade keji ti o waye ni ọjọ kedogun oṣu kẹwa ni Nigeria.
JIFORM, eyiti o ni awọn ọmọ-ẹgbẹ oniroyin ti o ju igba lọ, rọ awọn adari ile Afirika lati koju eto awujọ ati ọrọ-aje kaakiri Afirika lati ṣe idiwọ fun irin-ajo alaibamu.
Alaga ipade naa, Patrick Lumumba pe fun dida igbemọ ti o lodi si ifipa gbe ni rinrin-ajo ati ṣiṣe idokowo sori awọn ọdọ lati le ṣe idiwọ fun awọn ọdọ Afirika lati rinrin-ajo ainireti kọja aginju ati Okun Mẹditarenia.
O ju awọn eniyan 620 ti o ti rì tabi sọnu ni okun Mẹditarenia ninu igbiyanju lati de Yuroopu lati awọn eti okun Afirika ni ọdun yii, eyi ni ajọ IOM sọ .
Alakoso JIFORM, Ajibola Abayomi sọ pe awọn yoo pin iwe atokọ lori rinirin-ajo fun awọn oniroyin bii 10,000 kaakiri Afirika. Awọn aṣofin, oludari-ironu, awọn akọroyin ati awọn adaṣe awujọ ni o lọ si ipada naa ti o ni akori “iṣakoso irin-ajo ati imọran oniroyin fun idagbasoke”.
TMP_27/10/2020
Orisun Aworan: Shutterstock/AlejandroCarnicero
Akori Aworan: Ọkọ oju-omi ti o kun fun awọn arinrin-ajo ni ọjọ 3/3/2019 ni Okun Mẹditarenia, nitosi Lybia
Pin akole yii