Eto ise aso riran fun awon arinrinajo obinrin ni ile ise Gucci ti ta lore ebun ebayi

Isi awon obinrin lati orile ede Nigeria ti awon kan ko wole laibofunmu wo ile Italy fun owo eru tipatipa ni won ti ri ise tuntun si ile itaja ihunso ati apamonwo ti oruko re n je ” The New Hope Tailoring Cooperative” ti o wa ni ilu Caserta, ni orile ede Italy.

Ile itaja na ati awon arabinrin lati orile ede Nigeria ti won n sise nibe ni igbimon to n risi iboju aanu woni lawujo ti a mon si “Equilibrium” n’ilese ihunso Gucci ti fun ni egberun merin ojulowo aseéle aso ni kope-kope yii.  Equilibrium tun gbimonran lati pin awon eelo awo ati aso fun awon ile itaja Miran ti won n gba awon isi eniyan ti adeyesi sise.

Erongba ise na ni won fi lede ni ilu Roomu, ninu ifihan oge sise ti awon ahunso lati orile ede Nigeria se pelu iranlowo owo isi awon asonya akeko omo orile ede Italy eyi ti won kowon bi a se n ya ati ran awon aso awojade alafihan. Awon aso ti won se afihan re na won je adapo siliki Gucci ati satiini  ti won ni ounte ile Africa to mu yanyan.

Arabinrin abileko Rita Giaretta, eniti o n fi ile sowo fun awon arinrinajo ti won ba doola ni ariwa ilu Caserta, so fun iwe iroyin New York wipe afojusun ise na ni lati fun awon obinrin ni aponle nipase ise sise, ati lati din gbigbarale elomiran fun igbe aye to nitumo ku jojo.

“Fifunwon ni aponle Lo tumonsi mimu won pada si igbe aye won ati ki won o nigbagbo ninu ara won nigbagbogbo yato si igba ti won ba nilo nikan” Giaretta so bee.

O to egberun mewa si ogbon egberun awon omo orile ede Nigeria ti a nigbagbo wipe won n sise asewo ni orile ede Italy lowolowo. Opo ninu awon obinrin na ni won fi’pa mu wo’nu ise asewo lojuna ati le san gbese fun awon afinisowo ti won muwon rin irinajo wo orile ede Italy.

Ijoba orile ede Italo ti gbonwo si owo ti o n na lati se iranlowo fun awon arinrinajo ti won fe lati nile lori ni ile naa, sugbon awon lameeto awujo duro sori wipe ko tile tii si ohun eelo to to fun  lilo awujo na.

TMP – 27/06/2018

Orisun Aworan: http://www.nan.ng/business/lagos-tailors-to-begin-mass-production-of-clothes/

Migrating? Call our experts for advice

Aye n te si waju

Aye n te si waju – opolopo awon eniyan lo n rinrinajo lati ilukan bosikan lowolowo, beni opolopowon londojuko ipenija to lagbara ninu irin ajo won ni aye ode yi.

A o pese awọn otitọ ati iroyin to n sele lowolowo lori irinajo ni orisirisi ede ti yoo wa ni arowoto awon arinrinajo.

Mọ si