Obinrin mẹtala ku, ọmọ mẹjọ sonu lẹhin ti ọkọ oju-omi aṣikiri ti o kun ju ri nitosi Itali

Awọn olusọ eti okun Itali ti ri oku awọn aṣikiri obinrin mẹtala latinu ọkọ oju-omi ti o danu nitosi erekusu Italia ti Lampedusa ni Ojo Kefa Oṣu Kẹwa. Ọpọlọpọ awọn ti wọn wa ninu ọkọ oju omi naa si nsọnu, pẹlu awọn ọmọ mẹjọ. Awọn alaṣẹ Ilu Itali gbagbọ pe o ju awọn aadọta eniyan ti wa ninu ọkọ oju-omi naa ti o ti kuro lati Libya ki o to duro ni Ilu Tunisia lati ko awọn aṣikiri diẹ sii.

Awọn mejillelogun nikan ninu awọn ti o wa ninu ọkọ oju omi naa ti o ṣẹlẹ lẹhin ti awọn arinrin-ajo yara lọ si ẹgbẹ kan ti ọkọ oju-omi bi awọn alaṣẹ ti sunmọ. Enikan soso nikan ni wọn ti damo ninu awọn mẹtala ti o ye, pẹlu eyiti ọmọbirin ọdun mejila kan.

“Ọkọ oju omi ko si ipo lati gba ọna naa.” agbẹjọro ọmọ Itali Salvatore Vella sọ. Ni afikun, ko si ikankan ninu awọn arinrin-ajo naa ti o wo aso aabo lori omi.

Vella tun sọ pe pupọ ninu awọn arinrin-ajo naa wa lati Tunisia tabi Sub-Saharan Afirika.

Awọn olusọ eti okun ati awọn ọkọ ọlọpa ri ọkọ oju-omi aṣikiri naa ni kete ọganjọ oru, wakati pupọ lẹhin ti wọn gba ipe fun iranlọwọ, ibuso diẹ lati eti okun Lampedusa. Erekusu ti Lampedusa joko ni isalẹ Sicily o si jẹ oofa fun awọn aṣikiri ti n wa igbesi aye tuntun ni Yuroopu.

Opopona lati Tunisia si Ilu Itali, botilẹjẹpe o yara ku ju ti Libiya lo, ni eewu to po nitori bi okun naa ṣe gunju. Gẹgẹbi awọn agbẹjọro Sicili ti n ṣe iwadii ọran ọkọ oju-omi yii, ọna lati Tunisia ti di mimo gan larin awọn asasala ati awọn aṣikiri ti o n gbiyanju lati de Ilu Yuroopu, dipo awọn ewu.

 “Ete awọn ti o kuro lati Tunisia ni lati de etikun Sicili ni taarata ati lati dekun awon oluso,” Vella sọ.

Iṣẹlẹ tuntun yii ti mu iye awọn ti o ti ku lori okun Mẹditarenia ju 1,000 lo ni ọdun yii, eyi ti o se isọdọtun ibeere fun awọn igbesẹ lati yago fun awọn ajalu ọjọ-iwaju. Agbọrọsọ ti UN Refugee Agency (UNHCR), Charlie Yaxley, pe fun ajo EU lati tun bẹrẹ iṣẹ wiwa ati igbala rẹ ni Okun Mẹditarenia.

TMP 25/10/2019

Orisun Aworan: Nasib Demlite/ Shutterstock.com

Akole Aworan Obinrin mẹtala ti ku ati awọn ọmọ mẹjọ ti sonu nigbati ọkọ oju-omi aṣikiri kan ri ni erekusu Lampedusa.