Ẹgbẹẹgbẹrun awọn arinrin-ajo ni idaduro ni ilu Niger nitori coronavirus

O ju 2,300 awọn arinrin-ajo lọ, pupọ ninu wọn ti o jẹ ọmọ orilẹ-ede Naijiria, Mali, Guinea ati Kamẹruni, ni o ni idaduro ninu awọn ibudo irekọja mẹfa ti ajọ International Organization for Migration (IOM) n ṣakoso ni ilu Niger, Ijabọ lati Guardian sọ. Awọn arinrin-ajo na ti wọn n rinrin-ajo alaibamu lo si Ilu Yuroopu ni idaduro nitori awọn ihamọ ati titipa aala iwọle ni orilẹ-ede Niger ati awọn orilẹ-ede miiran nitori arun ajakaye coronavirus.

Ni ibẹrẹ oṣu, awọn ajinigbe rinrin-ajo fi 256 awọn arinrin-ajo silẹ ni aala Libya-Niger ṣaaju ki IOM to gba wọn. O kọja ọgọrun awọn arinrin-ajo ti wọn gbala na ni ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti wọ rinrin-ajo lọ si Yuroopu ni alaibikita ajakaye-arun coronavirus ati awọn titiipa aala.

Nitori ọpọ awọn arinrinrajo ti o wa ni awọn ibudo irekọja, IOM sọ pe awọn ibudo ti de ẹkun ati pe o n ṣawari awọn ọna lati mu awọn arinrin-ajo naa pada si orilẹ-ede abinibi wọn.

TMP_ 27/04/2020

Orisun Aworan: Shutterstock/Troy

Akore Aworan: Awọn oko nla fun irin-ajo lati Agadez ni Niger si Libiya.