Ọkọ oju-omi pẹlu 150 awọn arinrin-ajo ni iṣoro lori okun Mẹditarenia

O to 150 awọn arinrin-ajo ni wọn gbala lati ni Mẹditarenia lẹhin awọn iṣẹ igbala meji otọtọ ti ọkọ oju-omi Alan Kurdi ni eti okun Libya ni ojo kefa oṣu Kẹrin. Ṣugbọn Itali and Malta ko je ki ọkọ oju-omi naa duro si ilu wọn, eyi ti o tumo si pe awọn arinrin-ajo na si wa lori omi.

“Nkan ti o sele lori ọkọ ALAN KURDI n buru sii, bi ọkọ oju-omi igbala na ko yẹ fun ibugbe pipe ti awọn eniyan to o 150,” be ni Sea-Eye, NGO ti n ṣiṣẹ ọkọ oju omi naa, so ninu alaye kan ni Ọjọ Kewa Osu Kẹrin.

Ijọba Ilu Itali ṣalaye pe ajakaye-arun ti coronavirus ni idi wọn ko le gba arinrin-ajo naa ni akoko yii.

TMP_ 15/04/2020

Orisun Aworan: iStock/RanieriMeloni

Akori Aworan: Augusta, Sicily, Italy – Oṣu kejila ọjọ 11, 2013: Awọn arinrin-ajo n duro ni laini ni adugbo Sicili ti Augusta, nitosi ọkọ oju omi Amphibious San Marco.