Won gba opolopo awon arinrinajo la leba erekusu orile ede Libiya
Ko din ni ogofa odinmarun awon arinrinajo ni won ti doola leba ila oorun erekusu Libya ni owo ibere osu keje. Ifilede na ni awon omo ogun ojuomi ti orile ede Libya ti won ni ibasepo pelu ajo isokan awon orile ede ti a fi sori ijoba orile ede Libya.
Atejade na so pe awon arinrinajo na ti won je omo ile Africa ni won doola ni bi ibuso mewa to wa ni ariwa ilu Sorman ni orile ede Libya. Idoola emi na lo waye lasiko ti ipolongo igbogunti irinajo lona aito so ile alawofunfun ti rinle laarin awon orile ede ile Africa. Ninu isele to fara pe to waye ni ipari osu kefa, ogorun kan awon arinrinajo ni won teri sinu okun leyin ti Oko ojuomi won na teri l’eba erekusu orile ede Libya.
Agbegbe ariwa orile ede Libya ti di ibi aresepa fun awon arinrinajo to fe wo orile ede Italy ati awon orile ede alawofunfun miran, papajulo lenu igbati ijoba aarin gbungbun arile ede na ti dojude ni odun 2011.
Bakanna ni eka ajo isokan awon orile ede to n mojuto irinajo iom ti so pe o ju egberunkan awon arinrinajo to ti won ti teri sinu okun Mediterranean lati ibere odun yi nikan.
Nigbati o n soro nipa isele iku airotele to n sele ni kopekope yi, Oga agba fun ajo IOM si orile Libya Othman Belbesisi sope: “iku awon arinrinajo tile n lekun lemonlemon lori okun no eba erekusu orile ede Libya.”
TMP – 17/08/2018
Pin akole yii