Bi coronavirus ṣe n kan awọn arinrin-ajo
Lati ibere rẹ ni Wuhan China, coronavirus (COVID-19) ti tan si gbogbo awọn kontineti agbaye ayafi Antarctica ati pe o ju 600,000 eniyan ni o ti ni arun naa kariaye. Fun awọn arinrin-ajo ti rinrin-ajo lọ si tabi gbe ni Yuroopu, ajakaye-arun ti da isoro to pipo fun wọn.
Yuroopu je ilu ti o ni arun naa ju. O ti koja awọn 218,170 ti o ti ni arun naa ni ilu Yuroopu ni bi ọjọ karundainlogbon oṣu kẹta 2020. Nitori eyii, ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede ni Yuroopu ti paṣẹ awọn igbese to gbona eyiti o ni ipa lori awọn arinrin-ajo.
Lẹhin ipade kan ni ọjọ ketadinlogun oṣu kẹta, ni ajo European Union ṣe idaniloju awọn ona ibawole si ilu wọn nipasẹ idaduro irin-ajo ti ko ṣe pataki si agbegbe naa fun ogbon ọjọ. Kii ṣe Yuroopu nikan ni o se iru yii – awọn orilẹ-ede aadọta ti kede idaduro irin-ajo tabi awọn ihamọ awọn arinrin-ajo.
Ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede Yuroopu, pẹlu awọn orilẹ-ede miiran kaakiri agbaye, ti kede igbele jakejado orilẹ-ede, ti o tumọ si pe awọn olugbe ko le fi ile wọn silẹ ayafi ti pajawiri ba wa, bi rira ounjẹ tabi wiwa itọju. Awọn eniyan ti o ba rú awọn ofin wọnyi dojukọ awọn itanran tabi atimọle. Awọn arinrin-ajo ni Ilu Yuroopu tun wa labẹ awọn igbele yii ti oun mu ọpọlọpọ wọn nkọju ihamo ni awọn ibudo ati awọn ibe gbigba.
Awọn iṣẹ atilẹyin fun awọn arinrin-ajo ni wọn dawoduru bayii nitori aisi awọn oun ilera ati awọn ohun elo awujọ. Ni Ijọba Gẹẹsi, awọn olubo wa ibi aabo ti ko se aseyori ti wọn gbẹkẹle awọn alanu ati awọn ile ijọsin fun atilẹyin t wa laisi ounjẹ ati awọn ohun elo pataki, The Guardian lo so be.
Awọn ọkọ oju-omi ti o ṣiṣẹ igbala ni Mẹditarenia tun n dojuko awọn iṣoro ohunelo eyiti o nfa idibajẹ wiwa wọn ati awọn iṣẹ igbala. Awọn italaya wọnyi jẹ ki o lewu paapaa fun awọn aṣikiri lati kọja Mẹditarenia.
Awọn ẹgbẹ omoniyan tun ti gbe awọn ifiyesi dide fun awọn arinrin-ajo ti n gbe ni awọn ibudó ti o kunju lori awọn erekusu Greek. Fi fun aini awọn ohun elo, awọn ibudo ti ṣe apejuwe “ilẹ ibisi ti o lẹtọ” fun coronavirus.
Laarin rogbodiyan naa ni agbaye, awọn ipe wa fun irin-ajo ailewu ti o se deede ni ibamu pelu awọn eto Ajumọṣe Idagbasoke 2030 (SDGs) lakoko ti o n gbe awọn igbese gbo lati dinku itankale COVID-19 lati gbogbo awọn iduro pẹlu irin-ajo.
TMP _ 30/3/2020
Orisun Aworan: Shutterstock/DigitalMammoth
Akore Aworan: Maapu agbaye ti Coronavirus (Covid-19), Iwo-isunmọ awọn orilẹ-ede pẹlu Covid-19, Covid 19 maapu timo awọn ọran jabo kaakiri agbaye.
Pin akole yii