Germany yoo ma se idapada sile awon arinrinajo ni kiakia

Awon olopa ni ile Germany se akolu si ile awon oluwo to wa ni apa iwo oorun ilu Ellwangen ni ojo keta osu karun, iwode yi loje ojo keta leyin ti apapo awon arinrinajo kan se akolu pelu awon olopa lori fifisoworanse sile enikan to je omo odun metalelogun lati ilu Togo.

Akolu na loje abajade aato tuntun lori awon arinrinajo eyiti olori ile ise aato fun abenu ni ile Germany Horst Seehofer sese gbe jade.

Seehofer se ileri to lagbara lati fi opin si iwolu laibofinmu, mimu ki igbese lori ifarasin ni ilu na ya kiakia ati jije ki idapada awon olufarasin ti won ko gba wole ya kiakia bakanna.

“Ohun ti o sele na (ni Ellwangen) je idojutini ninu awujo awon eniyan ti won n bowo f’ofin” Seehofer so eleyi fun awon akoroyin nilu Berlin, gege bi iwe iroyin Associated Press send gbe.

“Eto lati bojuto ati ponle eniyan ko gbodo di tite mole be,” Seehofer so di mimo. O tun fikun pe awon eleto aabo yo sa gbogbo ipa to wa ni owo won ati Angbara won lati fiya to to labe ofin je awon ti won n fe lati farasin naa ti won dena awon olopa lati ma le da awon eniyan pada sile.

Awon olopa ile Germany so pe fifi ese ofin na rinle gbangba yamu ni awon se nitori idojuko ti awon omo ajo ohun ma n dojuko nigbati won ba fe my awon ti won ko gba wole fun ifarasin.

“Won tile ma n kodi won lati ma lee se be lona to buru jae lati owo orindinnigba si igba awon oluwo lati ile alawo dudu Africa,” Bernhard Weber igbakeji Oga olopa ni ilu Aalen legbe Ellwangen lo so bee.

Weber so pe won fi enu ikooko soodun lati fi oluwo omo ile Togo na sowo pada sile Italy, nibiti o gba wo ile Germany. Nibamu si ipinnu eyi ti ajo isokan ile Europe se ni Dublin, awon arinrinajo ni lati fi’fe han fun ifarasin ni ilu akoko ti won ba koko wo.

Gege bi otise wa ninu ipinnu ofin arinrinajo tuntun, ile Germany n gbero lati maa fi awon to n wa lati farasin wo so ibudo ti won ti pese fun olufarasin, nibiti won yo ti ma gbe pelu awon arinrinajo to to egberunkan ati eedegbeta arinrinajo miran fun awon asiko to to odun meji gbako. Won ko ni fi arinrinajo wo si awon ilu kaakiri titi ti won yoo fi gbawon wole fun fun ifarasin.

Awon adajo yo ma sise ninu ago awon olufarasin. Awon olufarasin ti won ko ba gba idirebe won wole ni won yoo ma fi sowo pada sile loju ese lati inu awon ago naa.

Seehofer tun fe lati se afikun onka awon irinse ti won fi n muni fun awon ti oro won ba ti ja si didapada sile lojuna ati ri daju pe won ko juba ehoro.

TMP – 30/05/2018