Pipese awọn odọdọ pataki nipa irin-ajo alaibamu
Ti o ba n ronu lati rin rin-ajo lo si oke okun abi o ba ti wa ni ọna, eto Migrant Project le fun ẹ ni awọn alaye pataki ti o se gbẹkẹle ni ọfẹ. A le sọ awọn eewu ti o wa lona fun ẹ ki o to bẹrẹ irin-ajo rẹ, ati bi igbesi aye ṣe ri ni tooto ni awọn orilẹ-ede irin-ajo kaakiri. A tun le ran ẹ lọwọ lati mọ nipa awọn ona lati rin rin-ajo to ba ofin mu, ikẹkọ tabi awọn aye iṣowo ti o sunmọ ẹ.
Awọn alaye to se gbẹkẹle nipa irin-ajo si orilẹ-ede titun soro lati ri. Awọn iroyin, agbeni rin rin-ajo, ati paapaa awọn eniyan to wa ni agbegbe rẹ ti won ti rinrin-ajo ri tẹlẹ le funni ni imọran ati alaye ti ko n se otito lori irin-ajo ati igbesi aye ni orilẹ-ede titun. Awọn agbeni rin rin-ajo yoo parọ lati gba owo. Ati pe ohun ti o jẹ otitọ fun arin rin-ajo kọn tele le ma jẹ be loni – awọn ofin ni awọn orilẹ-ede ma yipada, ati awọn ipa-ọna le ni eewu sii.
Awọn agbani nimọran agbegbe wa le fun e ni awọn alaye ododo to o le gbẹkẹle yala ti o ba n gbero lati rin rin-ajo lo si oke okun tabi ti o ba ti wa ni ọna. Eyi le je sisọro ni ojukoroju tabi lori foonu, nibi ti awọn oṣiṣẹ wa ti le dahun awọn ibeere rẹ. Awọn ibara ẹnisọrọ wọnyi jẹ oun ipamo nigbagbogbo. A tun ma n pese alaye lori ayelujara nipasẹ oju-iwe Facebook wa. O tun si le lo si awọn eto wa ni agbegbe rẹ ki o to ṣe ipinnu konkon nipa irin-ajo lo si ilu oke okun.